Lẹyin ti wọn fi maaluu ba oko ẹ jẹ, Fulani yin agbẹ lọrun pa niluu Baasi

Olu-theo Omolohun, Oke-Ogun

Ma f’oko mi paala, ọjọ kan naa la a kilọ rẹ ni ọkunrin agbẹ  ọmọ bibi orileede Olominira Bẹnẹ, Taminu Jugou, fọrọ ṣe latari ikilọ to lọọ ṣe fawọn Fulani pe ki wọn dẹkun dida maaluu wọn wọnu oko oun, lai mọ pe ikilọ naa yoo pada ja si iku ojiji fun un.

Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ l’Abule Agric, ti ko fi bẹẹ jinna siluu Baasi, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹ bawọn to fiṣẹlẹ naa to akọroyin wa leti ṣe wi, wọn ni lati bii ọsẹ meji sẹyin ni oloogbe naa to jẹ agbẹ alarojẹ, to si n kore oko rẹ lọwọ, ti n kilọ fawọn Fulani darandaran ti wọn n fi maaluu jẹko rẹ, ṣugbọn wọn ko gbọ. Wọn ni ọjọ kẹta lẹyin eyi lawọn Fulani mẹta mi-in tun ko maaluu wọn wọnu oko re, eyi la gbọ pe o fa a to fi lọọ fẹjọ sun ọba ilu naa lati ba oun kilọ fun wọn.

Ba a ṣe gbọ, deedee aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ naa, ṣadeede lawọn Fulani mẹta ti wọn dihamọra ya bo ile Taminu lẹyin toun atawọn mọlẹbi rẹ jẹun alẹ tan, nibi to ti n gbatẹgun ni wọn ka a mọ, ti wọn si yin in lọrun pa niṣoju awọn ọmọ rẹ, lẹyin naa ni wọn na papa bora.

Nibi ti oloogbe naa ti n japoro iku lọwọ ni ọmọ rẹ kan torukọ rẹ n jẹ Mark ti sare lọọ fọrọ naa to ọba ilu ọhun leti.

Loju-ẹsẹ la gbọ pe ọba naa ti pe awọn agbofinro lati ilu Agọ-Arẹ, ti wọn si palẹ oku naa mọ, wọn gbe e lọ sile igbokuu-si nile iwosan aladaani kan to wa niluu Agọ-Arẹ. Lara awọn agbẹ to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa koro oju si iṣẹlẹ ọhun, wọn si bẹnu atẹ lu bi Ọba Sunday Azeez ṣe faaye gba awọn Fulani darandaran lati maa fọwọ lalẹ, ti wọn yoo si maa yan fanda fanda laarin ilu lai naani awọn iwa iṣekupani to n waye latọwọ wọn.

Kọmandanti awọn Fijilante agbegbe naa, Oloye Ademọla Ọlawọọre, ti ni gbogbo agbara to wa nikaawọ awọn lawon yoo ṣa lati ṣawari awọn Fulani amookunṣika ti wọn sa lọ ọhun laipẹ.

Leave a Reply