Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin agbẹ kan ti wọn p’orukọ rẹ ni Sunday Ayẹni, lawọn araalu ti ṣawari oku rẹ nibi tawọn afurasi Fulani darandaran pa a si ninu oko ni Ùba Ọka Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii.
ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ buruku ọhun pe lati ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ni wọn loun ati aja rẹ kan to mu lẹyin ti kuro nile, to si dagbere oko.
Kayeefi lo jẹ fawọn eeyan rẹ nigba ti wọn ko ri i ko pada wale titi tilẹ ọjọ naa fi su, eyi lo mu ki awọn araalu kan gbera laaarọ ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, lati wa a lọ sinu oko rẹ to dagbere fun wọn.
Ṣe ni ibanujẹ dori gbogbo awọn to wa a lọ kodo pẹlu ipo ti wọn ba oku ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa ninu agbara ẹjẹ nilẹ ibi ti wọn ṣa a ladaa pa si, ti wọn si tun ba aja to mu lọ ati ada rẹ lẹgbẹẹ rẹ pẹlu.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun pe ọsẹ to kọja yii ni wọn lawọn Fulani kan lọọ fi maaluu ba gbogbo ire oko Sunday jẹ patapata, kete to ṣakiyesi eyi ni wọn lo pe awọn agbaagba ilu lati fi ọrọ naa to wọn leti.
Ibi tawọn agbaagba ọhun si pari rẹ si ni pe ki awọn Fulani naa san owo gba ma binu fun un gẹgẹ bii owo nnkan rẹ tí wọn fi maaluu jẹ.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ ibi ti wọn yanju ọrọ yii si ni ko tẹ awọn Fulani naa lọrun, leyii to mu ki wọn pada lọọ ka Sunday mọ inu oko lati gbẹsan owo ti wọn san lara rẹ.
Ninu ọrọ ti agba ilu kan, Alagba Pius Imoru, ba wa sọ nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun wa, o ni ibanujẹ nla lọrọ iku ọkunrin jẹ fun awọn niluu Ùba.
Imoru ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹ agbẹ ni ojulowo iṣẹ ti awọn n ṣe lagbegbe naa, sibẹ, ko sẹni to lori laya lati lọ sinu oko mọ nitori ibẹru awọn Fulani lati igba ti iṣẹlẹ buruku ọhun ti waye.