Lẹyin ti wọn gba miliọnu marun-un, awọn ajinigbe tu ara ilu oyinbo ti wọn ji gbe silẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni Muritala Adebayọ to fi ilu London ṣebugbe tawọn ajinigbe ji gbe ni agbegbe Ogele/Pampọ, nipinlẹ Kwara, gbominira l lẹyin ọjọ mẹfa to ti wa laahamọ wọn.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe, Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja, ni awọn ajinigbe ji Adebayọ gbe ninu oko rẹ to wa ni Ogele, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ti wọn si beere ọgọrun-un miliọnu naira owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi rẹ.

Adebayọ to jẹ ọmọ bibi ilu Ilọrin, to ti n gbe ni London lati ọdun pipẹ, sugbọn to wa sile lati waa maa dako, to si gba awọn oṣiṣẹ si oko ọhun, ni awọn ajinigbe lọọ ka mọ oko naa, ti wọn si ji i gbe lọṣẹ to kọja.

Inu igbo kan to wa ni agbegbe Okoolowo, niluu Ilọrin ni awọn ajinigbe ọhun ja a si  lẹyin ti wọn gba miliọnu marun-un owo idande.

 

 

 

Leave a Reply