Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn agbebọn to ji AbdulGaniy Misitura gbe lagbegbe Alagbado, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti tu u silẹ lẹyin ti wọn gba miliọnu marun-un Naira owo itusilẹ lọwọ mọlẹbi.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni awọn agbebọn lọọ ka oniṣowo pataki kan, Alaaja ti gbogbo eeyan mọ si Iya Misitura, mọle lagbegbe alagbado, wọn yinbọn pa ọmọkunrin rẹ, AbdulGaniy Musa, wọn tun gbe ọmọbinrin rẹ, Misitura, lọ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila oru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa yii, ni awọn agbebọn naa lọọ ka wọn mọle, ṣugbọn awọn eeyan naa ko ṣilẹkun fun wọn, ni nnkan bii aago mẹta ni wọn too ri ilẹkun ja wọle. Lati oju ferese ni wọn ti yinbọn pa Musa, nigba ti wọn wọle tan ti wọn ko ri Alaaja ni wọn gbe Misitura to jẹ ọmọ rẹ lọ, ti wọn si pe mọlẹbi pe wọn fẹẹ gba ọgọrun-un miliọnu Naira fun owo itusilẹ.
Ọkan lara awọn to n gbe ni agbegbe naa, Ọgbẹni Shehu, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe awọn agbebọn naa ti tu Misitura silẹ lẹyin ti wọn gba miliọnu marun-un Naira lọwọ mọlẹbi rẹ. Alaaja to jẹ iya rẹ si ti wa si agbegbe naa lati dupẹ lọwọ awọn araadugbo fun ipa ti wọn ko lori isinku ọmọ rẹ ọkunrin ti wọn pa, ati bi wọn ṣe ri Misitura doola lọwọ awọn ajinigbe.