Lẹyin ti wọn gba miliọnu marun-un naira, awọn ajinigbe yọnda iyalọja Isua Akoko atawọn mẹta mi-in

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iyalọja Isua Akoko, Oloye Edward Helen, atawọn mẹta mi-in to ku ninu igbekun awọn ajinigbe ni wọn ti fi silẹ nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii, lẹyin ti wọn ti san miliọnu marun-un naira ti wọn n beere lọwọ wọn.

ALAROYE gbọ pe Oloye Edward, alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ẹka Guusu Ila-Oorun Akoko atawọn yooku ni wọn ja sibi kan nitosi ilu Ọwọ, nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde.

Awọn iyalọja ọhun atawọn arinrinajo mẹẹẹdogun mi-in ni wọn rin si asiko tawọn agbebọn kan n ṣọṣẹ lọwọ loju ọna marosẹ Ọgbẹṣẹ si Ọwọ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.

Ọjọ keji iṣẹlẹ naa lawọn ọlọpaa ti sare jade, ti wọn si lawọn tí ri awọn bii mẹwaa gba pada ninu awọn ti wọn ji gbe naa.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni ọkan ninu awọn ọmọ Iyalọja Isua, Alaba Edward, pariwo pe iya oun ko si lara awọn ti ọlọpaa gba pada.

O ni oun ṣi ba iya oun sọrọ lọjọ naa to n bẹ oun pe kawọn tete lọọ wa miliọnu marun-un naira tawọn ajinigbe naa din owo ti wọn fẹẹ gba ku si.

 

Ọmọbinrin yii ni lẹyin tawọn san owo naa ni wọn too yọnda iya oun.

Leave a Reply