Lẹyin ti wọn gba owo nla, awọn ajinigbe tu akẹkọọ mẹrin ti wọn ji gbe l’Akoko silẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn akẹkọọ obinrin poli mẹrin ti wọn ji gbe lagbegbe lasiko ti wọn bọ nile fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi lopin ọsẹ to kọja yii ti gba itusilẹ lẹyin bii ọsẹ kan ti wọn ti wa ninu igbekun awọn to ji wọn gbe.

Olori awọn ọmọ ile to pọ ju lọ nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo nigba kan, Ọnarebu Sọji Ogedengbe, lo fidi itusilẹ awọn akẹkọọ ọhun mulẹ fawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le sọ iye tawọn ẹbi awọn ti wọn ji gbe ọhun san ni pato, sibẹ, ohun ta a ri gbọ ni pe owo nla lawọn agbebọn naa gba ki wọn too tu wọn silẹ.

Awọn mẹrẹẹrin ọhun, Ọbadẹrọ Florence, Arẹgbẹṣọla Ọrẹoluwa, Ahmed Ifẹoluwa ati Ọlarotimi Ọmọtoyọsi ti wọn n kẹkọọ lọwọ nile-iwe poli ipinlẹ Kogi pẹlu awakọ wọn, Mọmọdu, lawọn agbebọn ọhun ji gbe loju ọna Akunnu si Ajọwa Akoko.

Wọn ni ṣe ni idunnu subu layọ fawọn eeyan ilu Ajọwa ti i ṣe ilu abinibi awọn akẹkọọ ọhun lati igba ti iroyin itusilẹ wọn ti jade.

 

Leave a Reply