Lẹyin ti wọn gbowo, awọn agbebọn pa aburo ọba alaye ti wọn ji gbe ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Owurọ kutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni wọn ri oku Adegboyega Onijala, aburo Ọba ilu Ọlla, nijọba ibilẹ Isin, ti awọn agbebọn ji gbe lọ, ninu igbo kan nipinlẹ Kwara.

Tẹ o ba gbagbe ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja, ni awọn agbebọn to dihamọra pẹlu ohun ija oloro mi-in da Adegboyega lọna lasiko to n bọ lati inu iko rẹ to wa ni agbegbe iluu Ọlla, nijọba ibilẹ Isin, wọn n yinbọn soke lera lera ki wọn too gbe e lọ, ti a si tun ri ẹjẹ nibi mọto rẹ to han pe wọn ti ṣe e basubasu.

Lẹyin naa ni awọn ajinigbe pe mọlẹbi, ti wọn si n beere igba miliọnu owo itusilẹ, sugbọn awọn mọlẹbi ni miliọnu mẹwaa pere lawọn ri sa jọ, ti Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Tuesday Assayomo, si ṣeleri pe ileeṣẹ wọn yoo doola ẹmi ọkunrin naa laaye, ki wọn fi ọkan balẹ. Lara awọn mọlẹbi to sọrọ ti ko darukọ ara rẹ sọ pe wọn ti san diẹ ninu owo ti wọn n beere naa, ṣugbọn ni bayii, wọn ti ri oku Adegboyega ọhun ninu igbo kan ti awọn agbebọn naa rọra gbe e si.

 

Leave a Reply