Lẹyin ti wọn ge ẹya ara Hassana tan ni wọn ju iyooku ara ẹ sẹgbẹẹ ọna ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọdọmọbinrin kan torukọ rẹ n jẹ Hassana Muhammad, ni awọn afurasi oloogun owo seku pa, ti wọn si ju oku ẹ si ẹba ọna, lagbegbe Kanikoko, ni ijọba ibilẹ Kaima, Ariwa ipinlẹ Kwara.

Agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo (NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun ALAROYE. O ni lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni awọn afurasi oloogun owo ṣeku pa Arabinrin Hassana Muhammad, ti agbole Yarugaba, niluu Kaima, ti wọn si ju oku rẹ si Opopona Kanikoko, ni Kaima.

O tẹsiwaju pe awọn mọlẹbi ti kede pe awọn n wa arabinrin naa, nigba ti wọn pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ ti ko gbe e. Ṣugbọn awọn kan pada ta awọn ẹsọ alaabo lolobo, ti awọn fijilante si ba oku ọmọbinrin naa lẹbaa ọna.

Afọlabi ni lẹyin ayẹwo finnifinni ti wọn ṣe fun oku ọhun ni wọn ri i pe wọn ti fa oju ara ati ọyan rẹ lọ. Awọn mọlẹbi ti sin oku rẹ laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, nilana ẹṣin Musulumi.

Ọkunrin naa ni iṣẹlẹ ọhun ba ni lọkan jẹ, ati pe awọn yoo ṣe iwadii to muna doko lati foju awọn aṣebi naa han.

Leave a Reply