Lẹyin ti wọn pa ọba alaye, awọn agbebọn tun ji iyawo olori oṣiṣẹ Akeredolu lọ l’Ondo

Dada Ajikanje

Gbogbo ipa ni ijọba ipinlẹ Ondo n sa bayii lati ri i pe wọn gba iyawo Olori oṣiṣẹ lọọfiisi gomina, Ọgbẹni Olugbenga Ale, silẹ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn ji obinrin naa gbe niluu Owẹnna, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nipinlẹ Ondo.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe obinrin naa pẹlu awọn kan ti wọn jọ wa ninu mọto n bọ lati ipinlẹ Eko, ti wọn si n pada lọ siluu Akurẹ.

Laarin ọna ni awọn ajinigbe naa ti da mọto ti obinrin yii wa ninu rẹ duro, niṣe ni wọn si fa a bọ silẹ ninu mọto ọhun, ti wọn si wọ ọ wọ inu igbo lọ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

A ko ti i le fidi rẹ mulẹ boya oun nikan ni wọn ji gbe ninu ọkọ naa.

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa obinrin naa, awọn ajinigbe ọhun ko si ti i pe awọn mọlẹbi lati sọ iye owo ti wọn feẹ gba.

ALAROYE gbọ pe wọn ti fọrọ naa lọ ikọ Amọtẹkun lati ran wọn lọwọ lori bi wọn ṣe le ri obinrin yii.

Bakan naa ni wọn ni Gomina Akeredolu ti ṣabewo si awọn mọlẹbi ọkunrin yii, o si fọkan wọn balẹ pe obinrin naa yoo di riri.

One thought on “Lẹyin ti wọn pa ọba alaye, awọn agbebọn tun ji iyawo olori oṣiṣẹ Akeredolu lọ l’Ondo

  1. Nigbati, Elesin-sin nje Elegbo ko si eni ti o wi nkankan ……. Nigbati won npa awon Mekun-nun kini Awon Oba tabi ijoba odaran yi wi? Won wa pa Oba-alaye e wa npa ariwo were kiri! Ani kii awon Oba-alaye yii jeki Yoruba Nation da duro, won nwi ire-gbe, won nse eru Fulani kiri, nitori owo. Won nta Simenti ni #3,500, Baagi Iresi , #32, 000, Jara Epo-Moto #180, ko si ise, ko si Ounje, Kosi Abo rara. kisi ohun di o lo dede ni Nijiria . Ogede nbaje eni oun pon. Awon Ole Olo-selu ngba #30millon losu kan, won o de le san #30, 000 fun awon Osise! ,awon Ole Oba-Alaye naa ngba ti won, won fi se bamu-bamu ni wo yoo…… Ewo e ti ri nkankan, boya ti won ba pa Oba-Alaye Yoruba ku Meji, won a mo nka ti o kan wipe, asiko to lati da-duro! Igbeyawo tipaa-tipa yi ko so eso rere, Kilode ti a fi Ete sile npa Lapa-lapa naa? Ohun ti awon were-Fulani yii ndawon, se awa Omo Yoruba kan le dan ida-kan ninu e wo ni? Won fe pa gbaogbo wa ki wongba ile-wa bi won se gba Ilu-Ilorin lowo wa. Awon Olete-Oba kan si nwo, gbogbo awon Ole-Oloselu na nwo bakana nitori, Owo abi 2023 Ididbo. Ididbo ti koni waye lagbara Eledumare! Won sese bere ni, ti won ba to pa awon Oba-Alaye ti awon Oloselu fi je ati oni-jekuje ninu won tan,boya awon ti o ku a ji giri! Awon Ole gbogbo!

Leave a Reply