Lẹyin ti wọn pa ọlọpaa to n ṣọ wọn, awọn Hausa ji oyinbo mẹta gbe l’Ọṣun

Florence Babaṣọla

Lọwọlọwọ bayii, agbarijọpọ awọn oṣiṣẹ eto aabo nipinlẹ Ọṣun ni wọn wa ninu igbo abule kan ti wọn n pe ni Akere, nitosi Ifẹwara, nipinlẹ Ọṣun, lati ṣawari awọn oyinbo mẹta ti awọn Hausa kan ji gbe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe lebira lawọn ara iha Ariwa orileede yii naa n ṣe fun awọn oyinbo ọhun nibudo iwakusa kan nibẹ, ede aiyede ti ko si sẹni to mọdi ẹ lo ṣẹlẹ laaarin wọn ti wọn fi ji wọn gbe.

A gbọ pe wọn kọkọ pa ọlọpaa kan to n ṣọ awọn oyinbo naa ko too di pe wọn ji wọn gbe. Lẹyin wakati diẹ ti wọn ti ko awọn oyinbo naa lọ ni wọn bẹrẹ si i beere miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000).

Adari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Jẹnẹra Bashir Adewinbi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ko ti i si ẹnikankan to da awọn lebira naa mọ, ṣugbọn awọn ẹṣọ alaabo loriṣiiriṣii ti wa ninu igbo naa lati ri i pe wọn ri awọn oyinbo ọhun tu silẹ.

O ni awọn n ṣiṣẹ lati mọ ohun to ṣokunfa ede aiyede laarin wọn atawọn to ji wọn gbe, bẹẹ lo si daju pe ọwọ yoo ba wọn laipẹ.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun ajọ Sifu Difẹnsi l’Ọṣun, Daniel Adigun, sọ pe loootọ ni wọn ji awọn oyinbo mẹta gbe niluu Ifẹwara, wọn ko si ti i tu wọn silẹ.

Gbogbo igbiyanju lati ba Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọrọ lori iṣẹlẹ yii lo ja si pabo, nitori ko gbe ipe wa lẹẹmejeeji ti a pe e.

 

Leave a Reply