Lẹyin ti wọn paayan rẹpẹtẹ l’Ọwọ, awọn agbebọn tun paayan marun-un l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn agbebọn kan ni wọn tun ṣọṣẹ niluu Ondo to jẹ ibujokoo ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo loru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti ran eeyan marun-un mi-in sọrun ọsan gangan.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn agbebọn ọhun kọkọ lọ sọdọ awọn Hausa to wa lagbegbe Sabo, eyi to wa laarin gbungbun Ondo pẹlu ọkada ni nnkan
bii aago kan oru ọjọ naa, nibi ti wọn ti yinbọn pa eeyan mẹrin, ti wọn si tun ṣe ẹni kan leṣe.
Bi wọn ṣe n kuro nibẹ ni wọn mori le agbegbe kan ti wọn n pe ni Igba, loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ, ti wọn tun ti yinbọn pa ọmọ Hausa kan.
Nigba ta a fọrọ wa Alaaji Abdusalam Yusuf to jẹ Ṣeriki awọn Hausa niluu Ondo lẹnu wo, o ni ọkada meji lawọn agbebọn ọhun gbe wa si Sabo, ti wọn si jokoo ni mẹta mẹta lori ọkọọkan.
O ni Yoruba meji lo wa ninu awọn marun-un ti wọn yinbọn fun ni Sabo, awọn mẹrin lo ni wọn ku loju ẹsẹ, ṣugbọn ti ẹnikan yooku ṣi wa nile-iwosan ijọba to ti n gba itọju.

Alaaji Yusuf ni ounjẹ lawọn ọmọ Yoruba meji to wa lara awọn ti wọn pa ọhun waa jẹ ni Sabo loru ọjọ naa ki wọn too ṣe agbako iku ojiji nitori pe o ti wa ninu iwa ati iṣe awọn Yoruba kan lati waa maa jẹun lọdọ awọn Hausa.
Ọkan ninu awọn ọmọ Hausa ti wọn pa naa la gbọ pe o jẹ awakọ, ipinlẹ Katsina ni wọn lo ti n bọ loru ọjọ naa pẹlu ọpọlọpọ ẹru to n ko lọ si Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.
O ni bi awakọ naa ṣe de ọdọ awọn Hausa Sabo l’Ondo lo duro lati sun diẹ ko too tẹsiwaju ninu irinajo rẹ, oorun ọhun lo n sun lọwọ ti awọn agbebọn fi pa a ṣoju oorun.

Ṣeriki ni loootọ ni wọn tun lọọ pa ọmọ Hausa mi-in ni Sabo to wa ni Igba, lẹyin ti wọn ṣe ti Ondo tan.
O ni iro ibọn ti oun n gbọ lojiji lo ji oun loju oorun loru ọjọ iṣẹlẹ naa, jijade to jade sita lati wo ohun to ṣokunfa ibọn yiyin lo ni oun ba oku awọn mẹrin nilẹ ti ẹkarun-un wọn si n kerora ninu agbara ẹjẹ to wa.
Kiakia lo ni oun pe ọga ọlọpaa teṣan Fagun ti wọn si jọ gbe ẹni ti ko ti i ku ninu wọn lọ sile-iwosan ṣugbọn ti awọn dokita kọ jalẹ lati gba a lọwọ awọn, o ni ilẹ ti mọ tan ki wọn too pe awọn pada pe kawọn tun maa gbe ọkunrin naa bọ fun itọju.
Olori awọn Hausa ọhun ni awọn ti sinku awọn eeyan awọn lai fi akoko falẹ nigba ti ẹnikan yooku si n gba itọju lọwọ lọsibitu to wa.
Ariwo to kọkọ gba ilu kan ni kete ti iṣẹlẹ ọhun waye ni pe awọn eeyan tinu n bi kan lo lọọ ṣiṣẹ ibi naa lati gbẹsan bi awọn agbebọn ṣe lọọ pa ọgọọrọ awọn olujọsin mọ inu sọọsi Katoliiki Francis Mimọ, niluu Ọwọ, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni loootọ lawọn agbebọn lọọ paayan ni Sabo, niluu Ondo, ṣugbọn ipaniyan naa ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu ohun to waye l’Ọwọ.
O ni awọn adigunjale ti wọn lọọ ṣọṣẹ ni wọn paayan, ati pe ọrọ ọhun yatọ patapata sohun tawọn eeyan n gbe kiri.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: