Leyin ti wọn so yigi, iyawo gomina Kwara tun gba ile ati ṣọọbu fun Risikatu, obinrin toju rẹ yatọ

 

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Ọrọ ọhun tun da bii orin Wasiu Ayinde, to ni; ‘tẹtẹ rẹ ti jẹ’, fun obinrin to ni ẹyinju to yatọ niluu Ilọrin, Risikatu Abdulazeez ati ọkọ rẹ Abdulwasiu, pẹlu bi iyawo gomina Kwara, Olufọlakẹ Abdulrazaq, ṣe gbe kọkọrọ ile to ṣẹṣẹ gba fun wọn le wọn lọwọ.

Eyi ṣẹlẹ lẹyin ti wọn tun yigi so lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Pẹlu idunnu lawọn tọkọ-taya naa fi tẹwọ gba kọkọrọ ile fulaati oniyara meji ọhun to wa laarin igboro ilu Ilọrin.

Akọwe iroyin iyawo gomina, Ọlayinka Adeniyi, ni Olufọlakẹ gbe igbesẹ naa lati mu aye dẹrun fun tọkọ-taya ọhun nipasẹ ajọ Ajikẹ Support Group.

O ni iyawo gomina tun fẹẹ gba ṣọọbu fun obinrin naa, ti yoo si ra ọja oogun oyinbo to n ta tẹlẹ sinu ẹ fun un. Ṣugbọn nigba tawọn de ibi ti ṣọọbu ọhun wa, wọn ni ẹlomi-in ti sanwo rẹ.

O lawọn ti sọ fun obinrin naa lati wa ṣọọbu sibomi-in to ba wu u, ko si fi to awọn alakooso ajọ naa leti.

O fi kun un pe Arabinrin Olufọlakẹ yoo tun gba iwe aṣẹ fun Risikatu lati maa ta oogun oyinbo.

Leave a Reply