Adewale Adeoye
Ẹgbẹ awọn ẹya Ibo kan ti wọn n pe ni Ohanaeze Ndigbo, ti ki Sẹnetọ Godswill Akpabio ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo olori ileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa niluu Abuja ku oriire nla.
Ẹgbẹ naa sọ pe lara pe ibaṣepọ to dan mọran daadaa wa laarin awọn aṣofin ati ileeṣẹ aarẹ ilẹ yii ni wọn ṣe fẹnu ko, ti wọn sì yan Sẹnetọ Akpabio sipo olori naa bayii.
Atejade kan ti akọwe agba ẹgbẹ naa, Ikechukwu Isiguazoro, fi sita ti wọn fi ki Akpabio ni wọn ti beere nnkan mẹfa ọtọọtọ lọwọ olori awọn aṣofin yii.
Alukoro ọhun so pe, ‘’Ẹgbẹ Ohanaeze n lo akoko yii lati fi ki Sẹnetọ Akpabio ku oriire fun bi wọn ṣe yan an sipo olori nileegbimọ aṣofin agba ẹlẹẹkẹwaa bayii, a n lo akoko yii lati fi dupẹ lọwọ awọn ọmọ ileegbimọ naa pẹlu bi wọn ṣe tẹle ilana ati aba Aarẹ Tinubu to gbagbọ pe ipo pataki naa gbọdọ wa sí apa ilẹ Ibo, ki gbogbo ẹya le ni ipin ninu iṣakooso ijọba ilẹ yii.
Pẹlu bi Sẹnetọ Akpabio ṣe ti jẹ olori nileegbimọ aṣofin agba l’Abuja yii, o ti fi han gbangba pe ibaṣepọ to daa maa wa laarin ẹka ijọba mejeeji niyẹn. Ìgbàgbọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii ati tawọn ẹgbẹ Ohanaeze si ni pe, ibaṣepọ ọhun yoo mu ayipada rere ba awọn ọmọ orilẹ-ede wa laipẹ ọjọ.
Lara awọn ohun mẹfa tawọn ẹgbẹ naa n beere lọwọ Sẹnetọ Akpabio ni pe ko lo ipo rẹ lati ṣatunṣe si ofin ọdun 1999 ta a n lo nilẹ wa lọwọ yii.
Pe ki awọn aṣofin Naijiria wo ọna ti wọn le gbe e gba ti idagbasoke yoo fi de ba ilẹ Ibo laipẹ ọjọ
Bakan naa ni ẹgbẹ naa ni ki Akpabio ṣafikun ipinlẹ nilẹ Ibo lakooko rẹ. Eyi atawọn ohun miiran ni ẹgbẹ Ohanaeze yii n beere pe ki ọkunrin naa lo ipo rẹ gẹgẹ bii olori awọn aṣofin lati ṣe fawọn.