Lẹyin to ge ori ọmọ rẹ ati tẹnikan lati fi ṣoogun owo, Monday tun lọọ ge ori obinrin to ku lasiko ibimọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Monday Karezu lọkunrin to gbe ori eeyan dani yii n jẹ, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32) ni, ṣugbọn ori kẹta ti yoo ge lati fi ṣoogun owo lo gbe dani yii. Ori obinrin kan to ku lasiko ibimọ loṣu mẹta sẹyin ni.

Baba keji to wa lẹgbẹẹ rẹ ni wọn pe orukọ tiẹ ni Anagonou Kamelan, ẹni ọdun mẹrinlelogoji lo pe ara ẹ fawọn ọlọpaa to mu wọn nipinlẹ Ogun lọjọ Kẹta oṣu kọkanla yii, ọmọ orilẹ-ede Togo ni. Anagonou lo mu Monday lọ sile babalawo to fẹẹ ba a fi ori obinrin yii ṣowo, nibi ti ọrọ naa ti kan oun niyẹn.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa Ogun, ṣe fi sita, ni pe Monday to jẹ ọmọ bibi orilẹ-ede Olominira Bẹnnẹ, ti n wa ọna ti yoo fi lowo tipẹ.  Ọmọ rẹ obinrin to jẹ ọmọ oṣu mẹsan-an pere ni wọn lo kọkọ pa, to ge ori rẹ lọ fawọn ti yoo ba a fi ṣoogun owo, ṣugbọn oogun naa ko jẹ, o kan wulẹ fẹmi ọmọde naa ṣofo ni.

Lẹyin to ṣe ti ọmọ rẹ tan ni wọn lo tun lọọ hu oku ẹni kan, to ge ori iyẹn naa lati fi ṣawure owo, ṣugbọn  iyẹn naa ko tun jẹ fun un.

Nigba ti iyẹn naa ko ṣiṣẹ ni Monday fọrọ lọ Anagonou, iyẹn lo sọ fun un pe oun mọ babalawo kan to mọ oogun owo i ṣe gidi. O sọ fun Monday pe to ba le ri ori eeyan mi-in gbe wa lọtẹ yii, o daju pe awure to fẹẹ ṣe naa yoo jẹ, yoo si di olowo tabua.

Eyi ni Monday to n gbe lagbegbe Sabo, l’Abẹokuta, ṣe lọọ hu oku obinrin kan to ku nitosi ile rẹ, ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin ni wọn ni obinrin yii ku lasiko to fẹẹ bimọ.

Oku naa ni Monday hu, to ge ori rẹ to si gbe e sinu apo, o di ọdọ Anagonou to fẹẹ mu un lọ sile babalawo.

Awọn ko mọ pe olobo ti ta awọn ọlọpaa ẹka itọpinpin (SCIID), awọn iyẹn ti gbọ pe awọn ọkunrin meji kan n gbe ori eeyan lọ sile babalawo to fẹẹ ba wọn ṣoogun owo, wọn ti lọọ faraṣoko sibi kan de wọn, bi wọn si ti gbe ọkada de ile babalawo naa lawọn ọlọpaa yọ si wọn gulẹ, bi wọn ṣe mu wọn niyẹn.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, paṣẹ pe ki wọn ṣewadii iru iṣẹ ibi bayii to ṣee ṣe kawọn eeyan yii ti ṣe sẹyin, ki wọn si gbe wọn lọ si kootu fun igbẹjọ.

Leave a Reply