Lẹyin to ki wọn nile Akala l’Ogbomọṣọ, Tinubu ṣabẹwo si Gomina Makinde

Jọkẹ Amọri  

Nitori awọn iṣẹ ribiribi to ni o n ṣe nipinlẹ Ọyọ, Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, ti lu Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde lọgọ ẹnu.

O sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lasiko to ṣabẹwo si i nile ijọba niluu Ibadan, lati ki i ku ara fẹra ku ti Ọtunba Adebayọ Alao Akala to jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ to ku lọjọ kejila, oṣu ki-in-ni, ọdun yii.

Tinubu ni oun ki Makinde ku ara fẹra ku, bakan naa lo ki i fun bo ṣe gba a lalejo bo tilẹ jẹ pe akoko perete ni gomina naa fi mọ pe oun n bọ waa ki i.

Ninu ọrọ tiẹ, Gomina Makinde ni oun dupẹ fun abẹwo ti Tinubu ṣe naa. O ni bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu awọn ko papọ, ko fi eleyii ṣe to fi wa ki oun, eyi to fi han pe ki i ṣe oloṣelu ẹtanu.

Makinde lo asiko naa lati gbadura fun Tinubu lori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria, o ni ẹni ti o dara ju lawọn fẹ, ẹni to dara ju naa lo si daa ko bọ sibẹ niru asiko yii.

Ṣaaju abẹwo yii ni Tinubu ti kọkọ yọju si awọn mọlẹbi Oloogbe Alao Akala niluu Ogbomọṣọ, nibi to ti ki awọn mọlẹbi atawọn alatilẹyin gomina tẹlẹ naa.

Leave a Reply