Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lẹyin to ti lo ọjọ meje nigbekun wọn, awọn ajinigbe ti tu Oloye Idọlọfin ti Ijan-Ekiti, Emmanuel Babafemi, silẹ.
Bakan naa ni wọn tun tu awọn meji miiran ti ọkan lara wọn jẹ oniṣowo koko silẹ, ṣugbọn ALAROYE gbọ pe miliọnu mẹrin Naira ni wọn gba lọwọ
wọn lapapọ ki wọn to fun wọn ni iyọnda.
Oloye yii ati awọn meji naa ni wọn sọ pe wọn tu silẹ ni opopona to lọ lati Ikẹrẹ-Ekiti si Akurẹ, ni dede agogo mẹta orun ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ti wọn si ti darapọ mọ awọn malẹbi wọn.
Oloye Ọbafẹmi ni awọn ajinigbe naa ji ni ọna Ijan si Ado-Ekiti l’Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ to kọja, ti wọn si gbe wọn lọ si ibi ti ẹnikẹni ko mọ.
Awọn meji ti wọn jẹ oniṣowo koko ti wọn tun jigbe ni ọjọ Keresimesi ni wọn jẹ olugbe abule kan ti wọn n pe ni Ilupeju-Ijan. Oju ọna opopona Ijan si Isẹ-Ekiti ni wọn ti ji wọn gbe.
Ọkan lara awọn mọlẹbi Oloye Ọbafẹmi sọ pe Oloye yii san miliọnu meji, nigba ti awọn meji yooku san miliọnu meji, ki wọn too da wọn silẹ.
Alukoro awọn ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe loooto ni wọn ti yọnda awọn ti wọn ji gbe naa. Ṣugbọn oun ko mọ boya wọn san owo kankan.
O ni ọlọpaa ati awọn Amọtẹkun ṣiṣẹ takuntakun ninu igbo to wa ni gbogbo agbegbe naa, bakan naa lo ni awọn ọdẹ ibilẹ ko gbẹyin, ki wọn too ri awọn ti wọn ji ko naa gba silẹ.