Lẹyin wakati diẹ tawọn dokita bẹrẹ iyanṣẹlodi, awọn agbẹjọro ijọba naa bẹrẹ tiwọn l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Lẹyin wakati diẹ ti aọn dokita nipinlẹ Ondo bẹrẹ iyanṣẹlodi nitori owo-oṣu ti wọn ni ijọba jẹ awọn, ẹgbẹ awọn agbẹjọro to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ipinnu wọn la ti bẹrẹ iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ lori ọrọ owo-oṣu ati awọn ajẹmọnu mi-in ti wọn jẹ wọn.

Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ, Alaga fun ẹgbẹ awọn agbẹjọro ọhun, Ọgbẹni Babatunde Falọdun, ni awọn ìpinnu yii waye ninu ipade ti awọn ṣe lọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun 2020.

O ni lati bii ọdun mẹwaa sẹyin ni iya nla ti n jẹ awọn pẹlu bijọba ṣe kọ lati sanwo oṣu atawọn ajẹmọnu awọn.

Ọga awọn agbẹjọro naa ni ọjọ pẹ tawọn ti n pa kinni ọhun mọra lai pariwo, o ni iha ko kan mi nijọba n kọ si gbogbo arọwa ati ẹbẹ awọn la ti ọjọ yii wa.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ lo ni wọn ti pa ọkọ wọn ti latari airi owo ra epo, to jẹ ọkada lo ku tawọn n gun wa sibi iṣẹ.

O ni bi ọrọ naa tun ṣe n buru si i lasiko ijọba gomina to n ṣakoso lọwọ nipinlẹ Ondo lo sun awọn kan ogiri ti awọn fi pinnu lati fidi mọle, ki awọn si maa wosẹ niran titi tijọba yoo fi da awọn lohun.

Kọmisanna feto idajọ nipinlẹ Ondo, Kọlawọle Ọlawọye, ti fa ibinu yọ lori igbesẹ tawọn agbẹjọro naa gbe. Ọga agba fun ileeṣẹ eto idajọ ọhun ni o yẹ ki awọn amofin ọhun fi iṣẹlẹ yii to oun leti ki wọn too binu patapata.

O ni iyansẹlodi ikilọ lo yẹ ko ṣaaju ki wọn too kede ọlọjọ gbọọrọ tijọba ba kuna ati da wọn lohun.

Aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, kan naa lẹgbẹ awọn dokita oyinbo bẹrẹ iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ lẹyin ti wọn ti kọkọ fidi mọle fun bii ọjọ mẹta pere.

ALAROYE gbọ pe o ṣee ṣe ki ẹgbẹ awọn nọọsi ijọba naa bẹrẹ iyansẹlodi tiwọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lori ọrọ aisedeede owo-osu yii kan naa.

Leave a Reply