Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lẹyin bii wakati diẹ tawọn oniṣowo igi gẹdu fẹhonu han l’Akurẹ, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti pasẹ pe ki wọn ṣi gbogbo igbo ọba tijọba ti pa.
Kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Ọjọgo ni ijọba pinnu lati ṣi awọn igbo ọhun pada lẹyin ipade ti Gomina Akeredolu ṣe pẹlu awọn tọrọ kan lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun ta a wa yii.
Kọmiṣanna ọhun ni awọn atunṣe ti ijọba fẹẹ ṣe fun anfaani awọn araalu lo ṣokunfa titi igbo naa ni nnkan bii oṣu mẹwaa sẹyin.
O ni igbo naa yoo di ṣiṣi fun gbogbo awọn oniṣowo igi gẹdu to forukọ silẹ lọdọ ijọba bẹrẹ lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla, ọdun 2021, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lawọn oniṣowo igi gẹdu nipinlẹ Ondo pe jọ siluu Akurẹ lati fẹhonu han ta ko bi ijọba ṣe kọ lati si igbo ọba lẹyin gbogbo igbese tawọn ọba alaye ti gbe lori rẹ.