Oshodi ni wọn ti mu Lateef atọrẹ ẹ pẹlu ibọn ti wọn fi n digunjale

Faith Adebọla, Eko

Iwa ọmọde ni i mu ọmọde ṣoogun okigbẹ loootọ, pẹlu bọwọ awọn agbofinro ṣe tẹ awọn ọdọmọkunrin meji kan, Lekan Abdulateef, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Tajudeen Sanusi, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ibọn ati ọpọlọpọ oogun abẹnugọngọ ni wọn ka mọ wọn lọwọ, wọn lafurasi adigunjale ni wọn.

Oṣodi, nipinlẹ Eko, niṣẹlẹ yii ti waye laago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Mọnde yii, awọn ọlọpaa ayara-bii-aṣa, RRS, ti wọn n ṣe patiroolu kiri agbegbe ọhun lo kẹẹfin wọn lori ọkada, wọn lọna ti wọn n fi n gun ọkada naa mu ifura dani, ni wọn ba le wọn mu, wọn si fi pampẹ ofin gbe wọn.

Wọn lawọn mejeeji jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ọmọ bibi ipinlẹ Kwara lawọn, ṣugbọn agbegbe Ajegunlẹ ni ọkan loun n gbe, ekeji ni Orile-Iganmu nibugbe toun wa.

Nigba ti wọn bi Lateef leere pe bawo ni ti ibọn to gbe dani ṣe jẹ, o ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira loun ra a, ẹnikan lo si ba oun ra a.

Wọn tun lo jẹwọ pe niṣe loun n fi ibọn ọhun ja awọn onimọto lole, agbegbe Ọjọta si Maryland, titi de 7Up, China Town, Biriiji Eko lọ si Mile 2 lo lawọn ti n pa awọn eeyan lẹkun.

Kọmanda ikọ RRS Eko, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ti fidi ẹ mulẹ, iwadii si ti bẹrẹ lori awọn mejeeji. O lawọn ti taari wọn si olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa Eko, ibẹ lo ni wọn maa gba sọda sile-ẹjọ tiwadii ba pari.

Leave a Reply