Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọmọkunrin oniṣẹ-ọwọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Samuel la gbọ pe o ti para ẹ nipasẹ oogun apakokoro (Snippers) to gbe mu.
Iwadii ALAROYE lagbegbe Isalẹ Aro, niluu Oṣogbo, fidii rẹ mulẹ pe aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Samuel gbe majele naa mu. Lasiko to n jẹrora ninu ile ni ẹnikan ti wọn jọ n gbele gbọ, to si pariwo pe awọn araadugbo.A gbọ pe wọn gbe ọkunrin to n ṣiṣẹ birikila naa, lọ sileewosan aladaani kan lagbegbe ọhun fun itọju, ṣugbọn o dagbere faye nidaji ọjọ Aiku.
Ọkan lara awọn ti wọn n gbe pẹlu Samuel, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri, ṣalaye pe o ti kọkọ kuro ninu ile fun nnkan bii oṣu meji ko too di pe o pada de lọjọ Satide to kọja.
Ọkunrin yii ni “Bo ṣe di aarọ Sannde lo bọ sita, ti a si jọ n sọrọ. Ninu ọrọ wa lo ti sọ fun mi pe oun jẹ ọpọlọpọ awọn eeyan lowo, gbese ọrun oun si pọ.
“Mo gba a niyanju pe ọrọ gbese ko to o ro lasiko yii. Ko ju ọgbọn iṣẹju ti mo wọnu yara temi lọ ni mo gbọ to n jẹrora ninu ile, nigba ti mo maa yọju lẹnu ilẹkun rẹ, mo ba majele (snippers) lẹgbẹẹ rẹ.
“Bayii ni mo fariwo ta, a ranṣẹ si aburo rẹ kan to n gbe lorita Jalẹyẹmi, nitosi ibi, A kọkọ rọ epo pupa si i lẹnu ko too di pe a gbe e lọ sileewosan aladaani kan.
“Wọn bẹrẹ itọju rẹ, ara rẹ si ti n ya diẹdiẹ, koda, awọn ara inu ile gan-an lọọ bẹ ẹ wo lọsibitu lalẹ ọjọ Abamẹta, afi bo ṣe di aarọ ọjọ Aiku ti aburo rẹ waa sọ fun wa pe o ti ku.”
Nigba ti a pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, lori ọrọ naa, o ni wọn ko ti i fi to awọn leti.