L’Ọṣun, ori ko eeyan mejila yọ lọwọ iku ojiji

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Eeyan mejila lo bọ lọwọ iku ojiji nibi ijamba ọkọ to ṣẹlẹ loju ọna Ondo si Ifẹ lasiko ti ọkọ agbegi kan ati ọkọ bọọsi akero kan fori sọ ara wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Agbegbe Ẹgbẹjọda niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ṣe ni bọọsi akero naa to ni nọmba  BJN 375 XA run labala ibi ti awọn igi naa re si, bẹẹ ni awọn ero mejila ti wọn wa nibẹ fara pa, ṣugbọn ko si ẹni to ku ninu wọn.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ajọ ẹṣọ-ojupopo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, sọ pe ẹru akoju ati iwakuwa ọkọ lo ṣokunfa ijamba naa.

O ṣalaye pe ọkunrin mẹwaa ati obinrin meji ni wọn wa ninu bọọsi akero naa, bijamba naa si ṣe ṣẹlẹ ni ileeṣẹ ajọ naa to wa ni Ifẹtẹdo ti tete debẹ lati doola ẹmi wọn.

O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn ero inu ọkọ naa lawọn ti ko lọ sileewosan aladaani kan lagbegbe naa fun itọju to peye.

Leave a Reply