L’Ọṣun, Oyetọla di oludije fun ẹgbẹ APC, awọn TOP fidi-rẹmi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alaga igbimọ to ṣeto idibo abẹle fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Abdulrahman Abdulrasaq, ti kede Gomina Gboyega Oyetọla gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idibo naa.

Awọn mẹta; Gboyega Oyetọla to n ṣe gomina lọwọlọwọ, Alhaji Moshood Adeoti ti Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla fa kalẹ lati dije ati Ọnarebu Lasun Yusuf to gba fọọmu labẹ TOP, ni wọn kopa ninu idibo abẹle naa.

Nigba to n kede esi idibo naa nidaaji ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, Abdulrasaq sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn le ni ẹgbẹrun lọna irinwo (408,697) ni orukọ wọn wa ninu iwe akọsilẹ ẹgbẹ. Awọn ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din diẹ (247,207) ni wọn jade fun ayẹwo awọn oludibo, nigba ti awọn ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din diẹ (235550) jade dibo.

Lẹyin ibo ni Gomina Oyetọla ni ibo ẹgbẹrun lọna okoolelugba o le diẹ (222,169), Alhaji Adeoti ni ibo ẹgbẹrun mẹtala o din diẹ (12,921) nigba ti Lasun Yusuf ni ibo ọtalenirinwo (460).

Abdulrasaq sọ pe ni gbogbo ijọba ibilẹ ọgbọn to wa l’Ọṣun ni Oyetọla ti jawe olubori. O waa rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati wa niṣọkan, ki wọn si faaye gba ifẹ ẹgbẹ lati bori ohun gbogbo lọkan wọn.

Leave a Reply