L’Ọṣun, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣọ Job lọ sibi idibo abẹle APC, ni wọn ba yinbọn pa a

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wahala bẹ silẹ ni Wọọdu kẹfa to wa ni Odogbo, nijọba ibilẹ Atakunmọsa, nipinlẹ Ọṣun, lọsan-an ọjọ Abamẹta, nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lọọ ṣọṣẹ nibẹ.

Lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lagbegbe naa to sori ila lati yan oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun loṣu keje, ọdun yii, la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ori ila ni Akinọla Job wa ti awọn ọmọ-ẹgbẹ okunkun naa fi lọọ ba a, ti wọn si yinbọn fun oun nikan, loju-ẹsẹ lo si jade laye, koda, iya to bi i wa nibẹ.

Ọpalọla ni iwadii awọn ọlọpaa ti wọn wa lagbegbe naa fi han pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Job naa, o si ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ti wọn pa a ti n lepa awọn igun ti Job tẹlẹ ni wọn ṣe ṣọ ọ wa sile idibo.

O fi kun ọrọ rẹ pe lẹyin ti wọn yinbọn pa Job tan ni wọn sa lọ si ọna Iwara, bẹẹ ni awọn ọlọpaa le wọn. O ni, “Wọn doju ibọn kọ awọn ọlọpaa, ṣugbọn nigba ti ọwọ dun wọn ni wọn gbe mọto ti wọn gbe wa silẹ, ti wọn si sa wọnu igbo lọ pẹlu ọgbẹ ọta ibọn lara”

Ọpalọla sọ siwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n dọdẹ wọn kiri, ireti si wa pe laipẹ ni ọwọ yoo tẹ wọn.

Ohun ti awọn oloṣelu kọkọ n sọ ni pe awọn janduku ni wọn waa ṣiṣẹ naa, ko too di pe ileeṣẹ ọlọpaa tanmọlẹ si i.

A gbọ pe bọọsi kan to jẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn gbe wa, ṣugbọn iwadii ti fidi rẹ mulẹ pe iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ki mọto yẹn too kọja nibẹ.

Leave a Reply