Lọdun 2020, baale ile mejidinlaaadọrun-un lo fẹjọ sun pe iyawo awọn lu wọn lalubami l’Ekoo – Ijọba

Faith Adebọla, Eko

Bii apara lọrọ naa jọ, ṣugbọn ki i ṣe awada rara, ijọba ipinlẹ Eko lo sọ ọ, wọn ni akọsilẹ fihan pe leni, eji, mejidinlaaadọrun-un lawọn baale ile ti wọn waa fẹjọ sunjọba pe abẹṣẹẹ-ku-bii-ojo niyawo awọn, wọn ti fẹẹ fi lilu lalubami pin awọn lẹmi-in.
Kọmiṣanna lori ọrọ awọn obinrin ati eto leṣẹẹ-lugbẹ (Women Affairs and Poverty Alleviation) nipinlẹ Eko, Abilekọ Cecilia Bọlaji Dada, lo sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, nibi ayẹyẹ ọdun keji ti Gomina Babajide Sanwo-Olu di gomina ipinlẹ Eko, eyi to waye ni Alausa, Ikẹja.
Cecilia ni iwa ọdaran abẹle ki i ṣe iṣoro awọn obinrin nikan, bo ṣe wa ni liki naa lo wa ni gbanja, bo ṣe ri fawọn obinrin ti ọkọ wọn n ṣe baṣubaṣu, bẹẹ lohun tawọn ọkunrin mi-in n foju wina ẹ latọdọ awọn iyawo wọn kọja afẹnusọ.
Fun apẹẹrẹ, kọmiṣanna naa ni yatọ si awọn ọkunrin ti wọn fi ohun to n lọ labẹ ọọdẹ wọn to ijọba ati awọn agbofinro leti, ọpọ awọn ọkunrin lo jẹ pe iso inu ẹku ni wọn fi iya tawọn iyawo wọn fi n jẹ wọn ṣe, amumọra ni.
O ni lọdun 2020 to kọja yii, aropọ ọkunrin mẹrindinlaaadọta lo fẹjọ sun, tawọn si ṣakọsilẹ pe iyawo wọn fipa ba wọn lo pọ tabi fi ibalopọ halẹ mọ wọn.
Aropọ awọn ti ẹsun ti wọn mu wa tan mọ alubami latọdọ iyawo wọn jẹ mọkandinlaaadọrun, bẹẹ iwọnba eyi to de ọfiisi toun n ṣe kọmiṣanna le lori loun sọ yii, o ni oun gbagbọ pe ọpọ ẹsun bẹẹ maa wa lakọọlẹ awọn agbofinro bii ọlọpaa ati Sifu Difẹnsi, atawọn ileeṣẹ apẹtu-saawọ ati ajafẹtọọ ọmọniyan to wa kaakiri ipinlẹ ọhun.
Dada ni ṣugbọn ọdọ awọn obinrin ni kinni naa pọ si ju lọ, tori ọtalelẹgbẹta ati mẹrin awọn obinrin ni ọkọ wọn lu lalubami, tawọn si ṣakọọlẹ rẹ.
O ni ẹka ileeṣẹ ijọba toun jẹ kọmiṣanna le lori yii n ṣiṣẹ bii aago ni lati la awọn eeyan lọyẹ, lati rọ wọn, ati lati ja fun ẹtọ kaluku lori ọrọ yii, bẹẹ lawọn o ni i kaarẹ lẹnu ipese iranwọ lati mu adinku ba iṣẹ oun oṣi nipinlẹ Eko.

Leave a Reply