Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Bauchi, Alaaji Bala Mohammed, ti sọ pe bi agbara ba maa kuro lapa iha Ariwa, tabi ti ipo aarẹ yoo ba bọ si agbegbe mi-in, ki i ṣe lọdun 2023 to n bọ yii, o ni iha Ariwa ni ipo aarẹ ṣi gbọdọ bọ si ninu eto idibo to n bọ.
O ni loootọ ni pe awọn eeyan agbegbe mi-in kaakiri orileede yii ti n beere pe ki ipo aarẹ bọ si iha ọdọ awọn naa, ko si sohun to buru nibẹ, ṣugbọn awọn eeyan Ariwa/Ila-Oorun ni anfaani naa kan bayii, bo ba jẹ ori ododo ati aiṣojuṣaaju la fẹẹ gbe eto oṣelu orileede yii ka.
Bala sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lasiko ti igbimọ akanṣe kan to gbe kalẹ lati lọọ fikun lukun pẹlu awọn alẹnulọrọ lagbo oṣelu lori erongba rẹ lati jade dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023, n jabọ iṣẹ wọn fun un, niluu Bauchi.
Bala sọ pe: “A mọ pe awọn eeyan iha Guusu orileede yii ti n beere gidigidi pe ki ipo aarẹ bọ sọdọ wọn, tori saa iṣakoso olori wa, Muhammadu Buhari, to wa lati agbegbe Ariwa, yoo dopin lọdun 2023.
Mo fẹẹ lo anfaani yii lati sọ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mi, mi o si lẹgbẹ oṣelu APC o. Ẹgbẹ oṣelu APC lo ni iṣoro lati pinnu ibi ti wọn fẹẹ yi ipo aarẹ si. Ninu ẹgbẹ oṣelu tiwa, aarẹ to jẹ kẹyin wa lati agbegbe Guusu, aarẹ temi niyẹn, aarẹ tiwa niyẹn, Ọmọwe Goodluck Jonathan. Lasiko yẹn, ọdun mẹrindinlogun lẹgbẹ wa fi wa nipo, mẹrinla ninu ọdun yii, awọn aarẹ lati iha Guusu ni wọn lo o.
Ẹtọ ati ododo naa waa da to ba jẹ eeyan Guusu ni yoo tun bọ sipo aarẹ? Iha Ariwa lo kan. Tẹẹ ba wa si apa Oke-Ọya, saa perete ni iha Ariwa/Ila-Oorun ati Guusu/Ila-Oorun ṣi lo, ka sọ pe wọn kan fẹnu ba ipo aarẹ lasan ni.
Awa ni anfaani naa tọ si bayii, wọn gbọdọ fun wa lanfaani naa ni. Tori naa, ipo aarẹ yii, to ba jẹ lori ẹtọ ati ododo la fẹẹ duro le, ti ko si ojooro ninu ẹ, niṣe ni ka fun gbogbo eeyan lanfaani lati jade dije, ki i ṣe pe ki wọn yan agbegbe kan laayo lati mu aarẹ wa, ori-o-jori ni, kawọn ọmọ Naijiria si lominira lati yan ẹnikẹni to ba wu wọn ti wọn ro pe o maa tun orileede yii ṣe ju lọ, sipo.”
Bẹẹ ni Gomina naa wi.