Lọdun tuntun, meji ninu awọn oṣiṣẹ gomina Ondo ku ninu ijanba mọto

Meji ninu awọn ọga agba ti wọn je oṣiṣẹ Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ni wọn padanu ẹmi wọn lana-an ninu ijanba mọto to ṣẹlẹ lojuna marosẹ Ileṣa si Akurẹ.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe, ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Tosin Ogunbọdẹde ati ẹnikan lo ku ninu iṣẹlẹ ọhun.

Bẹẹ lo fi kun un pe ẹni kẹta ti wọn jọ wa ninu mọto ọhun wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii, ti wọn n gbadura gidigidi ki Ọlọrun da a pada saye.

Leave a Reply