Lọjọ ayajọ ijọba tiwa-n-tiwa, ẹlẹwọn mejidinlọgbọn gba idariji nipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lati ṣami ayajọ ijọba awa-ara-wa, Gomina Rotimi Akeredolu ti kede idariji fun mejidinlọgbọn lara awọn to n ṣẹwọn lọwọ lawọn ẹkun idibo mẹtẹẹta to wa nipinlẹ Ondo.

Ikede yii waye ninu ọrọ apilẹkọ rẹ lasiko ti wọn n sami ayajọ ijọba awa-ara-wa tọdun yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ bi alakalẹ ti gomina ọhun ṣe ninu iwe kan to fi ṣọwọ si olu ileeṣẹ ọgba ẹwọn to wa loju ọna Igbatoro, niluu Akurẹ, o paṣẹ pe ki wọn yọnda awọn ẹlẹwọn mẹtala ki wọn maa lọ sile wọn layọ ati alaafia.

Mẹwaa ninu awọn ẹlẹwọn ọhun ni wọn ti dajọ iku fun lo yi ijiya wọn pada si ẹwọn gbere, bẹẹ lo tun din idajọ ẹwọn gbere awọn ẹlẹwọn marun-un ku si ọdun perete.

Lẹyin eyi lo rọ awọn to ri aanu gba naa lati yago fun iwa ọdaran, ki wọn si ri idariji ti wọn ri gba naa bii anfaani lati wulo fun awujọ ti wọn n gbe.

Gomina Akeredolu tun fi asiko ayẹyẹ naa dupẹ lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari lori bo ṣe kede ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdọọdun, gẹgẹ bii ayajọ ijọba tiwa-n-tiwa.

O ni igbesẹ naa jẹ apẹẹrẹ rere, bẹẹ lo tun n ṣafihan pe ijọba apapọ ti Aarẹ Buhari n dari ti ṣetan lati fẹsẹ ijọba awa-ara-wa mulẹ lorilẹ-ede yii ju ti atẹyinwa lọ.

Leave a Reply