LONI-IN, AKEREDOLU YOO KOJU AWỌN ALATAKO Ẹ NINU APC L’ONDO

Boya Arakunrin Rotimi Akeredolu yoo tun ṣe gomina ipinlẹ Ondo lẹẹkan si i tabi ala ti ko ni i le ṣẹ ni, oni yii ni yoo mọ o. Idi ni pe loni-in yii ni wọn n dibo abẹle APC, awọn  mọkanla ni won fẹẹ dibo lati du ipo yii, ẹni to ba si jawe olubori ninu wọn ni ẹgbẹ yoo fa kalẹ lati du ipo gomina lorukọ APC.

Lati bii ọjọ mẹta kan ni wahala to le t iwa lọrun Akeredolu, lọdọ awọn ọmọ ẹgbe rẹ ti wọn jọ jẹ APC ni wahala ọhun si ti ba a ju lọ. Nidii eyi, ọpọlọpọ wọn ni ko fẹ ko pada di gomina lorukọ ẹgbẹ wọn mọ, awọn mi-in si ti titori ọrọ yii fi APC silẹ, ti wọn ba ẹgbẹ mi-in lọ. Ṣugbọn awọn mi-in ko lọ, wọn ni awọn yoo duro lati ri i pe awọn gba ipo naa lọwọ Akeredolu. Ohun tawọn ti wọn fẹẹ du ipo naa mọ ọn lọwọ ṣe jẹ mẹwaa ree, ti oun funrarẹ ṣe ikọkanla wọn.

Awọn mẹwaa yii ni, Jumọke Anifowoṣe, Oluṣọla Iji, Isaac Kẹkẹmẹkẹ, Ṣẹgun Abraham, Oluṣọla Oke, Jimi Odimayọ, Bukọla Adetula, Nathaniel Adojutẹlẹgan, Awodeyi Akinsẹhinwa ati Ọlaide Adelami. Awọn eeyan wọnyi ko sun mọju, torutoru n wọn n rin kaakiri lati mọ awọn ti wọn yoo sọ kalẹ fawon mi-in, ti wọn yoo lawọn ko ṣe mọ, ati awọn ti wọn yoo jọ darapọ lati koju ọta ati alatako wọn.

Ibo bọ-si-kọrọ-ko-o-di-i ni APC ni awọn fẹẹ di lati mu ẹni ti yoo du ipo gomina lOndo ninu oṣu kẹwaa yii, ohun ti Akeredolu fara mọ niyẹn, ṣugbon awọn oludije to ku yari, won ni ibẹrẹ ojooro ree, pe ibo gbangba-laṣaa-ta lawọn fẹ, ki wọn dibo naa loju-taye lo dara. Olori igbimọ to fẹẹ ṣeto idibo APC naa ṣaa, Gomina Yahaya Bello lati Kogi ti sọ pe awọn oludije kọ ni yoo paṣẹ fẹgbẹ, ohun ti ẹgbẹ ba gbe kalẹ ni wọn gbọdọ tẹ le, ohun ti ẹgbẹ ba ni ki wọn ṣe ni ki wọn ṣe.

Ko sẹni to ti i mọ bi ibo naa yoo ti ṣe lọ, boya akeredolu ni yoo bori awọn alatako rẹ, tabi boya awọn alatako rẹ ni yoo le e lọ.

Leave a Reply