Loootọ ni mo n lu ẹlẹhaa iyawo mi, ọdọ ọkunrin loun naa maa n yọ lọ lalẹ- Aafa Salami

Ọlawale Ajao, Ibadan

“Loootọ ni mo maa n lu u. Gbogbo igba ta a ba ti n sun lọwọ lalẹ lo maa n yọ kẹlẹkẹlẹ dide lẹgbẹẹ mi lori ibusun, ti yoo si lọọ ba bọ́ì kan ti oun naa rẹnti yara kan sinu ile merẹnti ta a jọ n gbe. Aimọye igba ni mo ti kilọ fun un pe ko yee maa lọ sibẹ laajin mọ ti ko gbọ, idi ti mo ṣe maa n  lu u niyẹn.”

Ọkọ ẹlẹhaa kan, Aafaa Naheem Salami lo ṣe bẹẹ sọrọ ninu awijare ẹ si ẹjọ ikọnisilẹ ti iyawo ẹ, Ẹlẹhaa Taiwo Salami pe e si kootu ibilẹ Ọjaba to wa ni Mapo, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.

Aafaa to n kọ awọn ọmọ ni keu nigboro Ibadan yii ṣalaye siwaju pe “Mo ti da majẹmu pe mi o ni i maa na an, ṣugbọn alaigbọran obinrin ni. Mo ti fẹjọ ẹ sun aafaa mi, wọn ti ṣe waasu fun un laimọye igba, ṣugbọn ko si ayipada kankan.”

Ṣaaju l’Ẹlẹhaa Taiwo ti rọ ile-ẹjọ lati tu yigi to wa laarin oun ati aafaa nitori tọkunrin naa maa n lu oun nigba gbogbo, igba kan si wa to lu oun ja sihooho toun ti bi oun ṣe jẹ ẹlẹhaa to.

Ṣugbọn olujẹjọ bẹ igbimọ awọn adajọ kootu naa lati ma ṣe tu igbeyawo ọhun ka nitori ọjọ iwaju awọn ọmọ ti obinrin ẹlẹhaa naa bi foun.

Gẹgẹ bii awijare olujẹjọ lati kọ ọkọ ẹ silẹ ni kootu, “Gbogbo igba ni wọn (aafaa) maa n lu mi. Koda, wọn maa lu mi lasiko ti mo ba wa ninu oyun ati nigba ti mo ba n tọ ọmọ lọwọ. Wọn maa n gbe mi ṣepe, wọn si maa n sọko ọrọ ranṣẹ sawọn obi mi.

“Iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fun mi nigba ti mo bimọ, awọn obi mi ni wọn sanwo ẹ fawọn dokita, ko si kọbọ ọkọ mi ninu owo yẹn.

“Nitori iya ti wọn fi maa n jẹ mi ni mo ṣe ko jade kuro nile wọn. Ileewe aladaani ni mo ko awọn ọmọ wa lọ ti Ọlọrun si n ran mi lọwọ lati ri owo ileewe wọn san. Ṣugbọn  ṣadeede lọkọ mi waa fi tipatipa ko awọn ọmọ kuro lọdọ awọn obi mi, to si ko wọn lọ sileewe ijọba. Nitori pe ko si fẹẹ nawo kankan lori awọn ọmọ ni.

“Latigba tawọn omọ ti pada sọdọ ẹ, iya buruku lo fi n jẹ wọn, Lọjọ ti mo ri awọn ọmọ yẹn gbẹyin, inu mi bajẹ nitori ẹkun ebi lawọn ọmọ yẹn sọ n sun.

“Mo rọ ile-ẹjọ yii lati tu igbeyawo wa ka, kẹ ẹ si jẹ ki awọn ọmọ wa pẹlu mi ki n le maa tọju wọn nitori alainikan-an-ṣe ni baba wọn, wọn, ko le tọju wọn rara.

“Ni ti ọdọ ọkunrin ti wọn ni mo maa n lọ, baba nla irọ ni, wọn o ka mi mọdọ ọkunrin kankan ri.”

Igbimọ awọn adajọ kootu ọhun, labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla, ti fopin si igbeyawo to seso ọmọ meji ọhun.

Ile-ẹjọ paṣẹ fun Aafaa lati maa san ẹgbẹrun mẹwaa Naira (N10,000) loṣooṣu fun ẹlẹhaa gẹgẹ bii owo ti yoo fi maa ṣeto ounjẹ fawọn ọmọ wọn mejeeji lẹyin ti wọn ti yọnda itọju awọn ọmọ naa fun olupẹjọ.

Leave a Reply