Loootọ lawọn eeyan wa kọju ija sawọn onifayawọ n’Ibarapa-Ileeṣẹ Aṣọbode

 

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan mẹta lo padanu ẹmi rẹ lasiko ifija pẹẹta naa to waye laarin ileeṣẹ aṣọbode atawọn eeyan ilu Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ.

Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, la gbo pe awọn ẹruuku kan ti wọn wọṣọ ileeṣẹ aṣọbodebile yii pẹlu aṣọ awọn ọmoogun orileede yii kọ lu awọn onifayawọ nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ.

Ṣugbọn awọn onitọhun paapaa ko gba a laabọ fun wọn, to jẹ niṣe ni wọn jọ fija pẹẹta pẹlu ibọn atoogun abẹnugọngọ.

Ninu ija ọhun ni wọn lọgaa ikọ Amọtẹkun ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa padanu ẹmi ẹ si.

Alukoro ajọ aṣọbode ilẹ wa, Theophilus Duniya, sọ pe oṣiṣẹ kọsitọọmu mẹta pẹlu ṣọja kan lo fara pa nibi iṣẹlẹ yii.

O ni bi awọn oṣiṣẹ kọsitọọmu ṣe ri awọn onifayawọ ọhun ti wọn n fi ọkọ mẹjọ ọtọọtọ ko ẹru lọ lọna ti ko bofin mu, ti wọn si gbiyanju lati da wọn duro lawọn onitọhun deede ṣina ibọn bolẹ fun awọn agbofinro, ti wọn si pa mẹta ninu wọn, ti awọn mi-in si fara pa.

Ọgbẹni Duniya fidi ẹ mulẹ pe ileewosan lawọn to fara pa laarin awọn agbofinro wa bayii, ti wọn ti n gba itọju, nigba ti iwadii n lọ lọwọ lati ri awọn arufin to yinbọn pa awọn oṣiṣẹ ijọba naa mu ki wọn le jiya to tọ sí wọn labẹ ofin.

 

 

Leave a Reply