Loootọ ni Baba Ijẹṣa fẹẹ fẹ mi, ṣugbọn mi o gba fun un – Princess

Faith Adebọla, Eko

Lori ẹjọ ti gbajugbaja alawada oṣere tiata ilẹ wa, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa n jẹ lọwọ ni kootu, Damilọla Adekọya ti inagijẹ rẹ n jẹ Princess ti ṣalaye pe loootọ lọrọ ifẹ waye laarin oun ati Baba Ijẹṣa, ṣugbọn o loun o ti i gba fun un.

Nibi igbẹjọ ọhun to waye lakọtun, lọjọ Aje, Mọnde yii, ni ile-ẹjọ giga to n gbọ awọn ẹsun akanṣe nipinlẹ Eko (Lagos State Special Offences Court) eyi to wa lagbegbe Ikẹja, lobinrin naa ti ṣalaye ara ẹ.

Princess lo lewaju ẹlẹrii ijọba ninu ẹsun ifipa ba ni lo pọ ati biba ọmọde ṣeṣekuṣe ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa.

Ṣaaju ni Baba Ijẹṣa ti sọ ninu igbẹjọ to kọkọ waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, lẹyin naa ni kootu ọhun fun afurasi ọdaran naa ni beeli lori ipilẹ ẹtọ ọmọniyan ati ilera rẹ, o kuro lahaamọ awọn ọlọpaa, wọn ni ko maa tile waa jẹjọ rẹ.

Nigba ti wọn pe Damilọla lati fidi ẹsun to fi kan Baba Ijẹṣa mulẹ, obinrin naa ni oun ni fidio kan to ṣafihan bi Baba Ijẹṣa ṣe ṣẹ ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn forukọ bo laṣiiri, baṣubaṣu nile oun. Obinrin naa ṣalaye pe ile oun lọmọ naa n gbe, o lawọn obi ọmọ naa lo fa a le oun lọwọ pe ko maa gbe ọdọ oun, ọmọbinrin naa si n kawe lọwọ.

Wọn bi i lere pe bawo waa ni Baba Ijẹṣa ṣe jẹ si i, o ni oṣere tiata ẹlẹgbẹ oun ni, ati pe loootọ lọkunrin naa dẹnu ifẹ kọ oun, to si ba oun sọrọ ọhun gidi, ṣugbọn oun ko gba fun un, ṣugbọn oun gba fun un lati jọ maa ṣe awọn fidio awada kẹrikẹri keekeekee ti wọn n gbe sori atẹ ayelujara papọ.

Princess tun ni oun n nawo nara lati ran Baba Ijẹṣa lọwọ lori igbesẹ lati kawe si i, ati lori ọrọ ilera rẹ, bo tilẹ jẹ pe igbeyawo oun ati ọkọ oun ti fori ṣanpọn ni gbogbo asiko ọhun.

Adajọ naa ni kawọn oniroyin yẹba diẹ na, lasiko ti wọn fẹẹ ṣafihan fidio ti Princess mu wa gẹgẹ bii ẹri ta ko Baba Ijẹṣa.

Lẹyin ti igbẹjọ tun bẹrẹ, Baba Ijẹṣa ko ti i sọrọ, niṣe nile-ẹjọ kede pe igbẹjọ naa yoo maa tẹsiwaju lọjọ keji, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Ijọba ipinlẹ Eko, eyi ti Ọgbẹni Ọlayinka Adeyẹmi n ṣe agbefọba fun lo wọ Baba Ijẹṣa lọ sile-ẹjọ lori awọn ẹsun mẹfa ọtọọtọ to tan mọ biba ọmọde ṣeṣekuṣe.

Amofin agba Babatunde Ọgala lo ṣaaju awọn agbẹjọro mẹtadinlogun mi-in ti wọn duro lati gbeja Baba Ijẹṣa.

Princess jẹ ẹlẹrii fun olupẹjọ, bakan naa si ni ọrẹ rẹ, Iyabọ Ojo, tẹle e wa si kootu fungba akọkọ, lati wo bi ẹjọ naa yoo ṣe lọ si.

Leave a Reply