Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti sọju abẹ nikoo pe loootọ loun ti figba kan ṣewọde ita gbangba ri nigba tawọn ijọba ologun fi wa nipo, ṣugbọn ki i ṣe eyi to da wahala tabi rogbodiyan silẹ laarin ilu loun ti kopa. Aarẹ Tinubu sọrọ ọhun di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii, lasiko to n gba Ọgbẹni Richard Mills, ti i ṣe aṣoju ijọba orileede Amẹrika lalejo lọfiisi rẹ niluu Abuja. Tinubu ni ko si ba a ṣe fẹẹ ṣọrọ ijọba dẹmokiresi ta a ni i sọ nipa iwọde ita gbangba, ṣugbọn ko si olori orileede kan tabi aṣaaju orileede to maa laju rẹ silẹ, to maa maa wọran pe kawọn kan waa fi wahala ba dukia awọn araalu ati tijọba jẹ. O ni, ‘‘Loootọ ni mo kopa pataki ninu awọn iwọde ita gbangba kan lasiko iṣejọba awọn ologun lorileede yii, a sọrọ ta ko iṣejọba wọn lasiko naa, mo si ranti daadaa pe mo wa lara awọn ti wọn ṣewọde ita gbangba lasiko naa, ṣugbọn ki i ṣe eyi to mu wahala ati rogbodiyan dani ni mo ti kopa. Wọọrọrọ ni gbogbo iwọde ita gbangba ti mo ba wọn kopa nibẹ waye, a ki i ja, bẹẹ ni a ki i ba awọn dukia araalu ati tijọba apapọ jẹ lasiko naa gẹgẹ bo ṣe wa bayii. A ti gbiyanju gidi lati nnkan bii ọdun mẹẹẹdọgbọn seyin bayii ta a ti n ṣejọba dẹmokiresi wa, ko yẹ ka doju rẹ bolẹ lori ohun ti ko to nnkan. Emi paapaa ṣetan lati daabo bo ijọba awa-ara-wa yii pẹlu gbogbo ohun ti mo ba ni’’. Aarẹ ni ki i ṣe ẹṣẹ pe ki awọn tinu n bi ṣewọde ita gbangba, ṣugbọn ko gbọdọ jẹ eyi to maa da wahala tabi rogbodiyan silẹ laarin ilu.