Gbenga Amos, Ogun
Iṣẹlẹ agbọ-ṣe-haa lọrọ ọhun jẹ leti awọn to n gbọ ọ, bawọn kan ṣe n sọ pe ‘abiru ki waa leleyii’ bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe opin aye lo de, latari bawọn ọlọpaa ṣe mu ojiṣẹ Oluwa ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Pasitọ Micheal Abiọdun, ti wọn fẹsun kan pe niṣe lo ki ẹgbẹ ọmọ ẹ, ọmọọdun mejila pere, to loun fẹẹ ṣe irapada fun mọlẹ, o mu un wọ yara kan ninu ṣọọṣi ẹ, o gba ibale ọmọ naa, o si fun un loyun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fọrọ yii to ALAROYE leti sọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹsan-an yii, pe adanwo nla kan lo ja lu iya ọmọbinrin naa, lairoti lọmọbinrin meji ti wọn jẹ ẹgbọn fun ọmọọdun mejila yii fo ṣanlẹ, ti wọn si ku. Ninu ibanujẹ ati ọgbẹ ọkan ni wọn ti sọ fun wọn pe ejo iṣẹlẹ naa lọwọ ninu, pe ki wọn tete wa aabo ẹmi tori ọmọbinrin kẹta, ki laburu kan ma tun lọọ ṣẹlẹ soun naa, eyi lo mu wọn de ṣọọṣi The Light House Gospel Church, to wa laduugbo Oluwo, ni Owode-Ẹgba, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode. Afurasi ọdaran yii si ni pasitọ ijọ naa.
Lẹyin ti wọn ti sọ ohun ti wọn ba wa, pasitọ ni ọrọ wọn ti dayọ, oun maa ṣiṣẹ irapada ẹmi fun ọmọbinrin ọhun ni o, oun maa ba wọn le iku jinna rere, tori ẹ, tiya rẹ ba ti dele, ko ma jafara, ko ran ọmọ rẹ wa fun akanṣe adura, iya naa si ṣe bi Pasitọ Micheal ṣe wi, laimọ pe niṣe loun fẹẹ lọọ fi ẹran ṣọ ologbo.
Nigba tọmọbinrin yii de ṣọọṣi, ṣe ni pasitọ mu un wọnu yara kan to wa layiika ṣọọṣi naa, adura ori bẹẹdi lo ṣe fun un, ibasun tipatipa lo ko bo ọmọọlọmọ, o si ṣe kinni ọhun karakara debi tọmọ naa fi di abara meji, oyun duro si i lara.
Iya ọmọbinrin yii tun ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oun ko tiẹ tete fura, tori ọmọ naa ko wi kinni kan nigba to dele, ọmọ ọhun ko si ti i bẹrẹ si i ṣe nnkan oṣu tẹlẹ, tori ẹ lo ṣe jẹ pe atoun atọmọ o mọ pe rẹrẹ ti run, pe ina ti jo wọn labẹ aṣọ, afigba ti oyun di oṣu meje, ti ikun tayọ aṣọ, lakara ba tu sepo.
Wọn beere ibi tọmọ to wa ni ipele keji nileewe girama akọkọ (JSS 2), ti wọn forukọ bo laṣiiri yii pe ta lo fun un loyun, sibẹ ko sọrọ, ko jẹwọ, rabaraba lo n sọ titi toyun naa fi pe oṣu mẹsan-an, to si bimọ ninu oṣu Kẹfa, oṣu Juunu, ọdun yii.
Lẹyin tọmọ ti ke, tiyaa si ti fọhun, lawọn mọlẹbi bẹrẹ si i lọ iya ikoko naa nifun pe ko yee fawọn ni igbo didi ṣan mọ, wọn ni ko jẹwọ bi oyun ṣe de, lọmọbinrin naa ba jẹwọ pe pasitọ ti mama oun ni ko ṣerapada foun lọjọsi lo loyun. Eyi lo mu iya ọmọbinrin naa lọọ fẹjọ sun ni tọlọpaa.
DPO ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Owode-Ẹgba, CSP Ọlasunkanmi Popoọla, ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ tẹle mama naa lọ sọdọ ojiṣẹ Ọlọrun yii, wọn de ṣọọṣi rẹ, wọn si mu un.
Ẹsin ki i jẹ oko abẹ ẹ la gbọ tawọn agba n powe, ṣugbọn nigba ti wọn bi Micheal leere ọrọ, ko jampata o, o ni loootọ ni, Oluṣọ-aguntan lo fi aguntan abẹ ẹ panu, amọ o tun ni ki i ṣẹbi oun naa ṣa o, Eṣu lo jẹbi, iṣẹ Eṣu ni.
Wọn tun beere lọwọ ọmọbinrin naa pe ki lo fa a ti ko tete jẹwọ fawọn obi ẹ, o ni pasitọ lo fa a, tori o ti kilọ gidigidi foun lẹyin to dide lori oun lọjọsi pe wiwo lẹnu awo n wo o, oun o gbọdọ sọ ohun to ṣẹlẹ fẹnikan, titi kan mama oun, tori toun ba fi le sọ pẹnrẹn, ajalu ati arelu loun fi n ṣere yẹn, eyi lo jẹ ko ṣoro foun lati sọrọ naa bi wọn ṣe n bi oun leere.
Ṣa, Pasitọ Micheal Adeyẹmi ti wa lakolo awọn ọlọpaa, ibẹ lo ti n ṣe iṣẹ ajihinrere ẹ lasiko yii, to si n ran awọn atọpinpin lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn tete pari iwadii, tori afurasi ọdaran gbọdọ tun alaye ati arojare ẹ sọ fadajọ laipẹ.