Loootọ ni wọn waa ṣewọde l’Akure, ṣugbọn n ko lọwọ si ‘Orileede Oodua’ ti wọn n pariwo-Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti sọ pe onikaluku lo ni ẹtọ lati ṣe iwọde alaafia, gẹgẹ bii iru eyi to waye niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejilelogun, oṣu yii, ṣugbọn ki ẹnikẹni ma darukọ oun si i pe oun n ṣatilẹyin fun iwọde naa, tabi pe oun fara mọ idasilẹ ‘Orileede Oodua’ tawọn to pe jọ naa lawọn n ja fun.

Ninu atẹjade kan ti gomina fi sita latọwọ Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlajide, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo ti sọ pe ‘’Awọn eeyan kan ti wọn kora wọn jọ, ti wọn ṣe iwọde niluu Akurẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, ti wọn lawọn n ja fun ‘Orileede Oodua’ n parọ pe awọn ni atilẹyin mi ni, eyi ko ri bẹẹ rara.’’

Gomina yii sọ latẹnu akọwe iroyin rẹ pe oun ko le di onikaluku lọwọ lati  ṣe iwọde alaafia niwọn igba ti ko ti ṣe lodi si ofin ilẹ wa, ṣugbọn eleyii ko sọ pe oun fọwọ si iwọde naa tabi pe oun ṣe atilẹyin fun ohun ti wọn n beere fun.

Akeredolu ni oun fọwọ si jijẹ ọkan ṣoṣo Naijiria gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn gomina ni iha Guusu ṣe fẹnu ko si, nitori eyi lo le mu anfaani lọwọ.

Atẹjade yii ko sẹyin bi ọkan ninu awọn ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Igboho, ṣe lọọ dara pọ mọ awọn ti wọn ṣe iwọde ti wọn fi n beere fun Orileede Oodua, to si sọ pe gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu, wa ninu awọn ti wọn n ṣe atilẹyin fun ijangbara fun orileede Yoruba ti wọn n beere fun yii.

Satide opin ọsẹ yii ni Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho sọrọ nibi iwọde naa to waye niluu Akurẹ, nibi to ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn Fulani ṣe n jẹ gaba le awọn ẹya to ku lori, ti wọn si n dunkooko mọ wọn. Pẹlu gbogbo ẹ naa, ijọba Buhari ko da awọn eeyan wọnyi lẹkun.

Leave a Reply