Loootọ nijọba jẹbi, ẹyin ọdọ, a tọrọ aforiji-Ọsinbajo

Olajide Kazeem 

Igbakeji Aarẹ orilẹ ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo, ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria lorukọ ijọba apapọ lori ipakupa ati ifiyajẹni lọna ti ko tọ, latọwọ awọn ẹṣọ agbofinro loriṣiiriṣi paapaa, awọn SARS.
Lori ikanni abẹyẹfo (twitter) ẹ lo kọ ọ si laṣalẹ ọjọ Ẹti, Fraidee, pe ijọba tọrọ aforiji gidi lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori nnkan ti oju wọn ti ri, paapaa bi wọn ṣe n wo ijọba pe ko ya sí ariwo awọn latijọ yii lori ipakupa ti awọn SARS n paayan ni Naijiria.
O fi kun un pe nibi ipade kan to waye niluu Abuja pẹlu awọn gomina ati minisita ilu Abuja lawọn ti fẹnu ko lati gbe igbimọ kan dide ti yoo ṣewadii lori ẹsun oriṣiiriṣii ti wọn fí kan awọn ẹṣọ agbofinro, paapaa awọn SARS. Bakan naa lo ni eto ‘gba ma binu’ yoo wa fun awọn eeyan ti wọn fiya jẹ lọna aitọ atawọn ẹbi awọn eeyan ti wọn ṣẹmi wọn lofo.
Bẹẹ gẹgẹ lo sọ pe awọn ẹṣọ agbofinro ti wọn fẹsun kan yoo kawọ pọnyin rojọ, ati pe ojutaye lawọn yoo fi eto ọhun ṣe, ti gbogbo agbaye yoo si ri i pe ijọba ṣe ohun to yẹ.
Ṣiwaju si i, o loun mọ pe ibeere awọn ọdọ Naijiria tayọ fifagile ẹṣọ agbofinro SARS nikan, ati pe gbogbo bi iwọde ọhun ṣe n lọ nijọba n fi oye tẹle wọn, ti igbesẹ si n lọ labẹlẹ lati ṣatunṣe sí ohun gbogbo ti wọn n beere fun.
Ọsinbajo ni lóòótọ́ lo yẹ ki wọn binu, ati pe Ibinu wọn, ohun to f’ẹsẹ mulẹ daaaa ni.

O loun gba pe ohun ti ijọba ṣe ku diẹ kaato, bẹẹ latunṣe sohun gbogbo ti wọn fẹ yoo bẹrẹ lọgan.

3 thoughts on “ Loootọ nijọba jẹbi, ẹyin ọdọ, a tọrọ aforiji-Ọsinbajo

  1. In fact we’ve vice president that has wisdom and well educated baba we know that you’re ready to do better but the cabal in your regime doesn’t allow you i pray Allaah will surely be with you sir

Leave a Reply