Lọọya f’ẹṣẹ fọ ekeji ẹ lẹnu niwaju adajọ, l’aṣọ funfun ba kun fun ẹjẹ ni kootu

Faith Adebọla

Orin wo la o kọ si gbẹdu lawọn eeyan n beere lori atẹ ayelujara lọwọ yii, lori fidio ati fọto awọn lọọya meji kan, Ọgbẹni John Yuwa ati Kingsley Mukna’an Guruyen, ti wọn binu gbe iwe-ẹjọ onibaara wọn ju ṣegbẹẹ kan ni kootu, ti ọkan si fi ẹṣẹ fọ ekeji ẹ lẹnu titi tẹnu rẹ fi bẹjẹ niwaju adajọ.

Kootu Majisreeti kan nipinlẹ Gombe la gbọ pe iṣẹlẹ yii ti waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Daniẹl Agabi, toun naa n ṣiṣẹ agbẹjọro sọ fawọn oniroyin pe:

“Mo mọ bọrọ ṣe jẹ gan-an tori niṣeju mi lo fi ṣẹlẹ, lọọya ti ẹjẹ ṣan si aṣọ ẹ yẹn, a jọ n ṣiṣẹ ni Ṣemba (Chamber) kan naa ni.

Lọọya ti ẹnu ẹ bẹjẹ yẹn lo n ro awijare ẹ lọwọ, ki lọọya keji tinu n bi too dide lọọ ba a nibi to wa, to si fun un lẹṣẹẹ lẹnu. Ẹnikeji ẹ o tiẹ da a lohun, o pe awọn ọlọpaa si ohun to ṣẹlẹ ni, awọn ọlọpaa si ti mu un lọ.

Loootọ lawọn kan n sọ lori atẹ ayelujara pe awọn mejeeji wọya ija ni, ṣugbọn irọ niyẹn, gbogbo iṣẹlẹ naa lo ṣoju adajọ to n wo ohun to n lọ.”

Ohun t’ALAROYE gbọ ni pe awọn lọọya mejeeji yii ni wọn ṣoju fun olupẹjọ ati olujẹjọ ninu igbẹjọ to n lọ lọwọ, ti nọmba iwe ẹsun rẹ jẹ CMCIII/GM/42/2017 laarin Hajiya Ladi Baba Umar ati Bilyaminu Shehu. Ọgbẹni Guruyẹn lo ṣoju fun olupẹjọ, nigba ti Yuwa ṣoju fun olujẹjọ.

Yuwa yii ni wọn lo n fesi ta ko alaye kan ti Guruyẹn ti kọkọ ṣe lori ẹjọ naa, ṣugbọn nigba ti ara Guruyẹn ko gba a mọ, niṣe lo fibinu dide, kaka ti i ba fi tọrọ aaye lọwọ adajọ pe ko ba oun da awijare ẹnikeji duro, ko sọ “ọbjẹkiṣan mai lọọdu” (objection, my Lord) rara, ẹṣẹ lo fi fesi alaye tẹnikeji ẹ n ṣe.

Bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa ṣe wi, iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ yii.

 

Leave a Reply