Lọọya Kunle alawada ṣegbeyawo bonkẹlẹ l’Ogbomoṣọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Ọpọ eeyan ni ko mọ pe Abdul-Gafar Abiọla, Cute Abiọla tawọn eeyan tun mọ si Lọọya Kunle, fẹẹ ṣegbeyawo. Afi lọjọ Ẹti to kọja yii ti ọdọmọkunrin alawada naa gbe arẹwa obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Kudirat Mosunmọla niyawo. Recreation Centre, niluu Ogbomọṣọ ni wọn ti ṣe e, ko si pẹ ti fidio ati fọto ayẹyẹ yii fi gba ori ayelujara kan.

Aṣọ oke alawọ buluu ni Lọọya Kunle atiyawo rẹ wọ, wọn tun wọṣọ funfun balau nibi kan, bẹẹ ni wọn n rẹrin-in muṣẹ bawọn alaga iduro ati tijokoo to dari ayẹyẹ idana naa ṣe n da orin aladun, ti wọn si n ṣadura nla nla fun wọn.

Bi igbeyawo yii ṣe ba awọn kan lojiji lawọn mi-in n sọ pe o ya awọn lẹnu pe Lọọya Kunle ko fẹ ọmọbinrin kan ti wọn jọ maa n ya fọto bii ololufẹ lori ayelujara, iyẹn Adedamọla Adewale ti wọn n pe ni ‘Ade herself.’

Ṣugbọn a gbọ pe ọna ti jin ti Cute Abiọla ati Kudirat ti n fẹra wọn, Ade herself paapaa ko si jiyan eyi, ohun to sọ ni pe oun ati Lọọya Kunle ki i ṣe ololufẹ, ọrẹ lasan lawọn.

O ni awọn ti wọn ro pe awọn n fẹra awọn ṣaa ti ri i wayi, pe Abdul-Gafar Abiọla ti fẹyawo tiẹ, eyi to fidi ẹ mulẹ pe ki i ṣe ọrẹkunrin oun bawọn eeyan ṣe n gbe e kiri.

 

Leave a Reply