Lọọya meji n kawọ pọnyin rojọ l’Ekoo, wọn ni wọn ṣe magomago ibo ẹgbẹ wọn

Faith Adebọla, Eko

Agbejọro gidi ni wọn loootọ, ṣugbọn wọn ko ri ẹjọ tara wọn yii ro o, ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa n’Ikẹja ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn agbẹjọro meji kan, Abilekọ Sarah Ajibola ati Ọgbẹni John Demide, sahaamọ EFCC. Wọn ko kowo jẹ o, ẹsun ṣiṣe magomago ibo ẹgbẹ awọn lọọya lo sọ wọn dero ahamọ.

Ẹsun mẹrinla ọtọọtọ ni wọn fi kan wọn, ṣugbọn eyi to lewaju ninu wọn ni pe wọn ṣe magomago ibo apapọ ẹgbẹ lọọya to waye lọdun 2018, lati ṣegbe sẹyin ọkan lara awọn oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ naa.

Agbẹjọro EFCC to jẹ olupẹjọ sọ pe niṣe lawọn mejeeji yii gbimọ-pọ, ti wọn lọọ yi akọsilẹ imeeli (email) ati nọmba foonu ẹgbẹrun kan o le mẹrin awọn lọọya ẹgbẹ wọn to yẹ ki wọn dibo pada, pẹlu ero pe ayederu akọsilẹ imeeli ati nọmba foonu ti wọn kọ ọhun ni wọn maa lo feto idibo.

Ohun mi-in ti wọn tun fẹsun rẹ kan wọn ni pe wọn kọ agbelẹrọ orukọ awọn oludibo loriṣiiriṣii, wọn si so wọn mọ awọn ile-ẹjọ ti ki i ṣootọ. Wọn ni wọn tun lọọ yii awọn iwe pataki kan pada ninu kọmputa ti wọn fẹẹ lo feto idibo naa.

Awọn olujẹjọ mejeeji lawọn o jẹbi. Agbejọro wọn, Abilekọ Deborah Ogundele ati Ọgbẹni N. E. Ogeibe, parọwa fun ile-ẹjọ lati faaye beeli silẹ fawọn afurasi ọdaran ti wọn di onibaara wọn yii, paapaa nitori agba lọọya ni Ajibọla, o ti lo ju ọdun mẹẹẹdogun lọ lẹnu iṣẹ naa, awo ko si gbọdọ dalẹ awo.

Adajọ Chuka Obiozor to gbọ aroye wọn ọhun sọ pe oun faaye beeli silẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta fun ọkọọkan wọn, pẹlu ẹlẹrii kọọkan ni iye owo kan naa, ko si ni dukia to jọju bii ile tabi ilẹ lagbegbe kootu ọhun. O ni ti ko ba ṣee ṣe fun wọn lati kaju ohun tile-ẹjọ la kalẹ yii, ki wọn maa lọọ gbatẹgun lahaamọ EFCC titi di ọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin, ọdun to n bọ.

Leave a Reply