Lori abọ iwadii EndSARS: Sanwo-Olu parọwa sawọn ọdọ lati jẹ ki alaafia jọba

Faith Adebọla, Eko

 “Loṣu Disẹmba, emi ni ma a ṣaaju eto yiyan bii ologun fun alaafia to maa waye lati bẹrẹ igbesẹ ọtun lati wo ilẹ wa san. Mo n lo anfaani asiko yii lati ke si awọn ọdọ wa, awọn aṣoju orileede gbogbo, awọn ẹgbẹ to n ja fẹtọọ ọmọniyan ati awọn oṣiṣẹ, awọn ọmọleewe ati awọn oniroyin ati gbogbo awọn tọrọ yii kan lati dara pọ mọ mi.

Mo fi tifẹtifẹ ke si Ọgbẹni Fọlarin Falana, ti inagijẹ rẹ n jẹ Falz, Ọgbẹni Debọ Adedayọ, ti inagijẹ rẹ n jẹ Mista Makaroni, Ọgbẹni Dele Farotimi, Temitọpẹ Majẹkodunmi, Ṣegun Awosanya, tawọn eeyan mọ si Segalinks, Adetoun, Ṣeun Kuti, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, Ọga agba ikọ RRS, CSP Yinka Ẹgbẹyẹmi, pe ki wọn jẹ ka jọ rin irin alaafia lọọ si Too-geeti Lẹkki, lọjọ naa.

‘‘Ẹ darapọ mọ mi, ka jọ rin irin yii fun ipinlẹ wa ọwọn, Ko sẹni to fẹẹ ba wa tun ilu yii ṣe fun wa, awa funra wa la maa ṣe e. Ẹ jẹ ka fi ẹni ta a jẹ han gbogbo aye. Ara Eko ni wa, a ni orirun atata, eeyan ti o kẹrẹ ni wa, a o si ni i juwọ silẹ lae.”

Eyi lawọn ọrọ ti Gomina ipinlẹ Eko fi kadii ọrọ akanṣe kan to ba gbogbo olugbe ipinlẹ Eko sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lori abọ iwadii EndSARS to n ja ranyin lorileede wa.

Ninu ọrọ rẹ ọhun, eyi ti wọn ta atagba rẹ lori tẹlifiṣan ati redio kaakiri ipinlẹ Eko, Sanwo-Olu daro bi iwọde EndSARS to ti n lọ wọọrọwọ ṣe yipada lojiji biri, to di eyi ti awọn janduku ja gba, ti oriṣiiriṣii iṣẹlẹ aburu ati ifẹmiṣofo si waye, lọdun 2020.

O latigba naa nijọba Eko ti n wa gbogbo ọna lati ṣatunṣe sawọn nnkan to bajẹ, ati lati pẹtu sọkan awọn tinu n bi lori iṣẹlẹ ọhun.

O fi da awọn olugbe Eko loju pe ijọba oun ko ni i lọkan lati figba kan bọ ọkan ninu lori abajade iwadii ti igbimọ ti wọn gbe kalẹ ṣe, ati pe bawọn ṣe maa bomi tutu sọkan awọn araalu, ti awọn si maa so okun ifẹ ati iṣọkan to yẹ kawọn eeyan fi maa gbe papọ lo jẹ ijọba oun logun, ki i ṣe bi wọn ṣe maa dawọ bo otitọ lori.

Sanwo-Olu ni nnkan to ṣẹlẹ ti ṣẹlẹ, wiwa atunṣe si i lo ku, ati bi iru rẹ ko ṣe ni i ṣẹlẹ mọ.

Leave a Reply