Faith Adebọla, Eko
Lori atundi ibo sipo sẹnetọ ẹkun idibo Ila-Oorun Eko to fẹẹ waye lọjọ karun-un, oṣu kejila, ọdun yii l’Ekoo, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti wọ Ọgbẹni Babatunde Gbadamọsi to jẹ oludije lẹgbẹ People’s Democratic Party, lọ sile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa n’Ikoyi, wọn ni kile-ẹjọ kede pe ko kunju oṣuwọn lati dije dupo ọhun.
Ẹsun meji ọtọọtọ ti wọn fi kan Gbadamọsi ni pe awọn magomago kan wa ninu iwe-ẹri to ko kalẹ fun ajọ eleto idibo, INEC, wọn ni gbarọgudu lasan niwe-ẹri to loun ni, ati pe ọkunrin naa tun bura eke labẹ ofin.
Agbẹjọro fun ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko, Amofin agba Kẹmi Pinheiro, ati ẹlẹgbẹ rẹ, Kẹmi Balogun, ni wọn kọwe ẹsun lọjọ Aje, Mọnde yii, n’Ikẹja, lorukọ onibaara wọn, APC.
Ninu iwe ẹsun ọhun, wọn tun pe ajọ eleto idibo lẹjọ, wọn ni ko yẹ ki wọn tẹwọ gba iwe-ẹri ti Gbadamọsi ko ṣọwọ si wọn, ko si yẹ ki wọn fi orukọ rẹ kun awọn to peregede lati kopa ninu eto idibo to wọle de tan ọhun.
Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu APC l’Ekoo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aje naa, o ni awọn ti bẹbẹ pe kile-ẹjọ tete ba wọn gbọ ẹjọ ọhun, ki idajọ le tete waye lori ẹ ki ọjọ idibo to o de.
Ṣa, Ọgbẹni Gbadamọsi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP, ko ti i fesi kan lori iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn ireti wa pe wọn yoo sọ igbesẹ ti wọn ba fẹẹ gbe lori ọrọ naa di mimọ laipẹ.