Lori ẹsun agbere, wọn da olukọ Fasiti FUOYE duro

Taofeek Surdiq, Ado Ekiti

Latari ẹsun pe o fọgbọn alumọkọrọyi ba akẹkọọ kan ni yunifasiti ijọba apapọ FUOYE to wa ni ilu Oye-Ekiti, igbimọ alaṣẹ ileewe naa lawọn ti da olukọ agba kan, Dokita Jonathan Mbachaga, duro lọgan.

Olukọ naa to jẹ ọkan ninu awọn ọga ni ẹka eto ẹkọ ere ori itage ati iroyin (Theatre and Media Art) ni wọn sọ pe o ba ọmọ ileewe ọhun to wa ni ipele kẹrin nileewe naa ni ajọṣepọ pẹlu ero pe ko le fun un ni maaki lẹyin igba ti akẹkọọ naa ti fidi-rẹmi nigba meji leralera.

Gẹgẹ bii lẹta kan ti Oludamọran lori eto iroyin si ọga agba FUOYE naa, Ọgbẹni Folusho Ogunmọdẹde, ṣe wi, o sọ pe ọga agba pata ọhun lo paṣẹ pe ki olukọ Mbachaga ṣi lọọ rọọkun nile fun igba kan, lẹyin igba ti wọn gba a mu pẹlu ẹri to daju pe o ṣẹ ẹṣẹ naa.

Wọn sọ pe olukọ naa ba akẹkọọ ọhun laṣepọ nigba meji leralera, to si tun kọ lati fun un ni maaki to ṣeleri, eyi ni wọn sọ po bi akẹkọ-binrin naa ninu to pariwo olukọ Mbachaga yii sita.

Ninu lẹta naa, wọn ṣalaye pe igbesẹ dida olukọ yii duro lọgan jẹ lati faaye silẹ fun igbimọ ẹlẹni marun-un kan ti igbimọ alaṣẹ ileewe naa gbe kalẹ lati ṣewadii ẹsun yii.

Ọga agba Fasiti ọhun sọ ninu lẹta naa pe oun ko ni i faaye silẹ fun idọti laarin olukọ ati ọmọ ileewe, ati pe gbogbo olukọ to ba jẹbi ọrọ ninu iṣẹlẹ yii lawọn yoo fọwọ osi juwe ile fun.

Leave a Reply