Lori ẹsun ijinigbe ati ipaniyan, eeyan mẹrin foju bale-ẹjọ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun wọ awọn afurasi mẹrin lọ lori ẹsun pe wọn ji ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, Kazeem Alli, gbe, ti wọn si tun pa a.

Alli, ẹni to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn awakọ NURTW niluu Apomu, nijọba ibilẹ Iṣọkan, ni awọn janduuku kan ji gbe logunjọ oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lagbegbe Oke-Afa, niluu Apomu.

Lẹyin ti wọn ji ọkunrin naa, ti inagijẹ rẹ n jẹ Kekere Pasuma, gbe ninu mọtọ rẹ, Toyota Corolla, to ni nọmba APM 203 AA, lalẹ ọjọ naa ni wọn pe iyawo rẹ, Jẹmila, pe ki wọn wa miliọnu mẹẹẹdogun Naira wa gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Ere owo yii lawọn mọlẹbi rẹ n wa kaakiri to fi di pe awọn janduku naa ko ba wọn sọrọ mọ, bẹẹ ni nọmba ti wọn fi n pe iyawo rẹ ko lọ mọ, ileeṣẹ ọlọpaa si sọ nigba naa pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi mẹjọ.

Ni kootu lọjọ Iṣẹgun, awọn ọlọpaa ko awọn afurasi mẹrin wa, awọn naa ni Fatai Owolabi, ẹni ọgọta ọdun, Akinọla Isiaka, ẹni ọdun mọkandinlọgọta, Sẹmiu Agbeyangi, ẹni ọdun mọkandinlọgọta ati Arimiyau Abiọla to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji.

Agbefọba, Inspẹkitọ Elisha Oluṣẹgun, ṣalaye pe iwa ti awọn afurasi naa hu lodi si abala okoolelọọọdunrun o le mẹrin, okoolelọọọdunrun o din ẹyọ kan, okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹrin ati ọtalelọọọdunrun o le mẹrin abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Kootu ko gba ẹbẹ awọn mẹrẹẹrin, agbẹjọro wọn, J. Akano, bẹbẹ pe ki kootu da ẹjọ naa pada si kootu ilu Apomu, nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Adajọ A. K. Ajala sọ pe ki wọn fi awọn afurasi naa pamọ sakolo ọlọpaa titi digba ti wọn yoo tun fara han nile-ẹjọ Majisreeti ilu Apomu.

Leave a Reply