Lori eto aabo, ijọba ibilẹ Atisbo ro awọn ọdẹ ibilẹ lagbara

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Lati le jẹ ki eto aabo tubọ rẹsẹ walẹ si i nijọba ibilẹ Atisbo, alupupu Bajaj mẹwaa ni ijọba ibilẹ naa pin fawọn ọlọdẹ agbegbe yii, eyi ti ayẹyẹ rẹ waye lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ni Sẹkiteria ijọba ibilẹ Atisbo.

Ninu ọrọ Adari awọn aṣofin nijọba ibilẹ naa, Ọnarebu Taiwo Adekunle, jẹ ko di mimọ pe eto aabo mumu laya Gomina Ṣeyi Makinde, idi niyi to fi pa a laṣẹ fun gbogbo ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn nipinlẹ Ọyọ lati ri i pe wọn ṣe koriya fawọn ọdẹ ibilẹ, awọn fijilante, atawọn ọlọpaa agbegbe wọn.

Ninu ọrọ Alaga ijọba ibilẹ ọhun, Ọnarebu Fasasi Adeagbo Ademọla, ni awọn gbe igbesẹ yii nibaamu pẹlu aṣẹ latọdọ Gomina latari bi eto aabo ṣe mẹhẹ lorileede yii, paapaa nijọba ibilẹ Atisbo to ni ilẹ ati arọko to pọ ju ni tibu-tooro ipinlẹ Ọyọ.

O waa rọ awọn ti wọn janfaani ọkada naa lati lo o lọna to tọ kawọn araalu le sun oorun asundiju lai si wahala kankan.

Lara awọn ti wọn pin ọkada naa fun ni awọn ọlọdẹ ibilẹ lati ilu Agunrege, ilu Irawọ Owode, Baasi, awọn ọlọpaa, atawọn ọtẹlẹmuyẹ.

Lakooko to n fesi, Balode ilu Irawọ Owode, Oloye Ogunlade Oguntolu, ati akẹgbẹ rẹ lati ilu Baasi, Oloye Oluwaṣẹgun Adeoti ni awọn ti fọkan araalu balẹ pe ki gbogbo wọn ma foya, awọn yoo sa gbogbo agbara awọn lati ri i pe ijọba ibilẹ naa wa lalaafia, ṣugbọn awọn nilo ifọwọsowọpọ wọn ki kaluku joye oju lalakan fi n ṣọri lati le ṣaṣeyori.

Leave a Reply

%d bloggers like this: