Lori iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ, awọn ọlọpaa mu Dokita Adedoyin to ni Otẹẹli Hilton

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ti sọ pe awọn ti mu Alaga ileetura Hilton Hotel and Resorts, Dokita Ramon Adegoke Adedoyin, latari iku to pa akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan laipẹ yii, Timothy Adegoke.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe ti fi to yin leti, ọjọ keje, oṣu kọkanla yii, ni Timothy, ẹni to n fimọ kun imọ ni ẹka Fasiti Ifẹ wa siluu Moro, lati Abuja, to si gba yara ni Hilton Hotel, lẹyin to san ẹgbẹrun lọna mẹtadinlogoji naira fun oorun ọjọ meji.

Nigba to di pe awọn mọlẹbi rẹ ko ri i ba sọrọ la gbọ pe ọkan lara wọn to jẹ ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ iwadii lori ẹ.

Iwadii wọn fi han pe ọkunrin naa wọle si ileetura Hilton, o si fi han pe o sanwo sinu akanti ọmọbinrin kan to jẹ oṣiṣẹ ni otẹẹli naa.

Wọn lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa ilu Ẹdunabọn leti, wọn si ko mẹfa lara awọn oṣiṣẹ ileetura naa. Ọjọ keji ni wọn taari wọn lọ si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran niluu Oṣogbo.

Nigba ti wọn bẹrẹ iwadii la gbọ pe awọn ọlọpaa ri oku ọmọkunrin naa.

Ninu atẹjade kan ti Ọpalọla fi sita lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lo ti sọ pe awọn ti mu Dokita Ramon Adedoyin lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, o si ti wa lakolo awọn fun iwadii.

O ni awọn ti gbe oku ọmọkunrin naa lọ sileewosan fun ayẹwo nipa ohun to pa a gan-an, pẹlu ileri pe ko si ẹni to lọwọ ninu iku rẹ ti yoo lọ lai jiya.

Amọ ṣa, awọn igbimọ Mayẹ niluu Ileefẹ (Mayẹ-in-Council) ti kegbajare si awọn ọlọpaa lati ṣewadii to kunna lori iṣẹlẹ naa nitori Dokita Adedoyin ko le hu iru iwa ti wọn fẹsun kan an pe o hu.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Oluṣẹgun Jẹjẹ fi sita lorukọ igbimọ naa ni wọn ti sọ pe ẹni to ti la oniruuru ipenija aye kọja ni Adedoyin, ko si si bi eeyan ṣe le wa laye ko ma ni elenini.

Wọn ni kileeṣẹ ọlọpaa tuṣu desalẹ ikoko iṣẹlẹ naa ki olododo ma baa ku sipo ika.

Leave a Reply