Lori iyọnipo igbakeji gomina, adajọ-agba Ondo ja ireti awọn aṣofin kulẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Adajọ-agba ipinlẹ Ondo, Abilekọ Oluwatoyin Akeredolu, ti ja ireti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo kulẹ lori igbesẹ ti wọn n gbe lati yọ Ọnarebu Agboọla Ajayi nipo gẹgẹ bii igbakeji gomina.

Ọjọru, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ọhun kọwe si onidaajọ naa gẹgẹ bii ilana ofin ti wọn si pasẹ fun un lati ṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni-meje ti yoo ṣewadii ẹsun ti wọn fi kan Agboọla lẹyẹ-ọ-sọka.

Oni, ọjọ Ẹti, Furaidee, ni adajọ-agba da esi iwe wọn pada, ninu eyi to ti kọ jalẹ pe ohun ti wọn n beere fun naa ko ni i ṣee ṣe rara.

Onidaajọ Akeredolu ni iye awọn aṣofin ti wọn fọwọ si iwe iyọnipo naa ko ti i to ida meji ninu mẹta gẹgẹ bii alakalẹ iwe ofin orilẹ-ede yii tọdun 1999.

Awọn aṣofin mẹsan-an ti wọn tako iyọnipo yii ni wọn kọkọ kọ iwe si ọga awọn adajọ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti wọn si fi ẹdun ọkan wọn han lori igbesẹ tawọn akẹgbẹ wọn n gbe lọwọ lati jawe gbele-ẹ fun wọn ki wọn le baa tete ri igbakeji gomina yọ.

Wọn rọ onidaajọ ọhun lati kiyesara ko ma si ṣe dawọ le ohunkohun to le tako ofin orilẹ-ede Naijiria.

Leave a Reply