Lori ọrọ Hijaabu, ijọba Kwara paṣẹ kawọn ileewe ti wahala ti ṣẹlẹ wọle

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman AbdulRasak, ti paṣẹ pe kawọn ọmọleewe lawọn ileewe mẹwaa kan ti wọn ti pa latari wahala ọrọ Hijaabu wiwọ to da awuyewuye silẹ, pada sẹnu ẹkọ wọn, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ninu atẹjade kan lati ọfiisi Akọwe agba lẹka eto ẹkọ ipinlẹ naa, Abilekọ Kẹmi Adeọṣun, gba ẹnu gomina sọrọ, o ni ijọba ti paṣẹ fawọn akẹkọọ ati olukọ lawọn ileewe mẹwaa tọrọ naa kan lati so ọlide ti wọn n lo lọwọ yii rọ na, ki wọn si bẹrẹ ikẹkọọ wọn lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun yii.

O ni aṣẹ naa pọn dandan ko baa le ṣee ṣe fawọn akẹkọọ naa lati jere awọn ẹkọ ti wọn padanu lasiko tijọba fi tilẹkun ileewe wọn ninu oṣu keji to kọja yii, nigba ti fa-a-ka-ja-a ọrọ wiwọ ibori awọn obinrin ẹlẹsin Musulumi ti wọn n pe ni Hijaabu n gbona girigiri.

Atẹjade naa ni kawọn ileewe tọrọ naa kan ṣi maa gbadun asiko ọlide wọn titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ti gbogbo ileewe pamari ati sẹkọndiri maa bẹrẹ saa eto ẹkọ kẹta (third term) papọ.

Abilekọ Kẹmi ni igbesẹ yii ṣe pataki, ko ma baa si idarudapọ ninu eto ẹkọ, ki awọn akẹkọọ naa si le ba awọn ẹlẹgbẹ wọn ti ọrọ Hijaabu wiwọ o kan, mu.

Gomina waa parọwa sawọn obi, olukọ atawọn akẹkọọ lati gba alaafia laaye, ki wọn si jẹ ki adehun ati ajọsọ to ti wa laarin awọn alaṣẹ ileewe atawọn olori ẹsin lori ọrọ wiwọ Hijaabu lawọn ileewe fẹsẹ mulẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, to kọja yii, nijọba paṣẹ ṣiṣi awọn ileewe mẹwaa to jẹ ti awọn ẹlẹsin Kristẹni, latigba ti wọn ti ti wọn pa ninu oṣu keji, tori awọn olori ẹsin nileewe naa sọ pawọn o ni i gba wiwọ Hijaabu laaye nileewe wọn.

Leave a Reply