Lori ọrọ Igangan, mo gba gbogbo ẹbi tẹ ẹ da mi, ṣugbọn iru ẹ ko ni i waye mọ-Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan ilu Igangan, ni agbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, lori iṣẹlẹ iṣekupani to tun waye niluu naa ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Gomina naa to de ilu yii ni nnkan bii aago marun-un kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn, to si bawọn araalu naa sọrọ ni gbọngan ilu yii tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan ilu Iganagan ati Ibarapa lapapọ.

Makinde ni oun mọ pe oun ja awọn eeyan ilu naa kule lori eto aabo, ṣugbọn ki wọn jọwọ dariji oun, oun si ṣeleri fun wọn pe eyi ni yoo jẹ igba ikẹyin tiru iṣẹlẹ naa maa waye.

O ni awọn yoo mu eto aabo agbegbe naa ni ọkunkundun ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ, gbogbo awọn ẹṣọ alaabo to si wa ni adugbo naa lawọn yoo ṣamulo lati ri i pe eto aabo to rinlẹ wa nibẹ.

Leave a Reply