Lori ọrọ SARS: Sanwo-Olu gbe igbimọ oluwadii kalẹ fun idajọ ododo

Faith Adebọla, Eko

Latari ipade tawọn gomina ṣe pẹlu ijọba apapọ lati bu omi tutu sọkan awọn ọdọ tinu n bi lasiko yii, ati lati ṣatunṣe si awọn ohun to wọ latẹyinwa lori ẹsun aye alabata tawọn ọlọpaa ikọ SARS ti jẹ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti ṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹfa kan ti yoo gbọ awọn ẹsun tawọn araalu ba mu wa lodi si iwakiwa ikọ SARS.

Gomina sọ eyi di mimọ ninu ipade to ṣe pẹlu awọn akọroyin nile ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Marina, l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, o ni igbimọ onidaajọ naa yoo wadii awọn ẹsun ti wọn ba mu wa ta ko iwa buruku eyikeyii ti SARS ti hu nipinlẹ Eko, wọn yoo si tun damọran bijọba ṣe le ṣatunṣe to yẹ fun ẹni to jare, ati iru iya ti wọn maa fi ẹnikẹni to ba jẹbi jẹ.

Adajọ-fẹyinti Doris Okuwobi lo maa jẹ alaga igbimọ naa gẹgẹ bi gomina ṣe wi, awọn marun-un to ku ni: Amofin agba Ẹbun Adegboruwa, Ọlọpaa-feyinti DIG Taiwo Lakanu, Abilekọ Patience Udoh, Ọgbẹni Ṣẹgun Awosanya to jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, ati Abilekọ Olutoyin Odusanya. Oṣu mẹfa gbako ni wọn yoo fi ṣiṣẹ wọn.

Bakan naa ni gomina tun kede awọn nọmba tẹlifoonu tawọn araalu maa pe si ti wọn ba fẹẹ ba igbimọ yii sọrọ tabi ti wọn fẹẹ mu ẹsun wa. Awọn nọmba naa ni: 09010513203; 09010513204 ati 09010513205. O ni igbimọ naa ti bẹrẹ iṣẹ lati ọjọ Aje, Mọnde yii.

Bakan naa ni gomina tun kede eto ikowojọ igba miliọnu naira lati fi ran awọn ti wọn ba fẹri ẹ mulẹ pe loootọ ni SARS ti fiya jẹ wọn lọna aitọ kan, lọwọ. O ni ijọba oun gba lati gbọ ohunkohun tawọn araalu ba lawọn n fẹ, tori araalu gan-an lo ni agbara.

Leave a Reply