Lori owo Naira tuntun, awọn gomina APC mẹta wọ Buhari rele-ẹjọ

Faith Adebọla

 Gbọnmi-si-i-omi-o-to-o to n waye latari ipaarọ owo Naira atijọ si tuntun to n lọ lọwọ lorileede yii ti tun gba ọna mi-in yọ wayii, esuro ti padi da, o ti n le aja, awọn gomina mẹta ninu ẹgbẹ oṣelu to n ṣakoso lọwọ, All Progressives Congress (APC), Gomina ipinlẹ Kaduna, MallaM Nasir El-Rufai, ti ipinlẹ Zamfara, Bello Matawale, ati ti ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ti wọ Aarẹ Muhammadu Buhari lọ sile-ẹjọ, koda wọn o duro nile-ẹjọ giga tabi ti ko-tẹ-mi-lọrun rara, ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa ni wọn kọri si taara, wọn ni ki wọn gbọ ẹbẹ awọn, ki wọn paṣẹ fun Buhari, ijọba apapọ ati banki agba ilẹ wa, iyẹn Central Bank of Nigeria (CBN), pe ki wọn jawọ lori gbedeke ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ti wọn lawọn eeyan o ni i le naa owo atijọ naa mọ, ki wọn wọgi le deeti naa, ki wọn si fun awọn eeyan lanfaani lati nawo ọwọ wọn, ibaa jẹ tuntun o, ibaa si jẹ tatijọ, bo ṣe wu wọn.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Keji yii, lawọn gomina mẹtẹẹta ọhun gbe igbeṣẹ akin yii, nipasẹ awọn kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ kaluku wọn, ti wọn si pawọ-pọ gba lọọya kan, Amofin agba AbdulHakeem Uthman Mustapha, wọn pe Minisita feto idajọ nilẹ wa, Malam Abubakar Malami, lẹjọ lati ṣoju fun Buhari ati ijọba apapọ.

Lajori ẹbẹ ti wọn tẹ pẹpẹ rẹ siwaju ile-ẹjọ to ga ju lọ ni pe ki wọn paṣẹ fun Buhari ati Emefiele, ti i ṣe Ọga agba banki apapọ ilẹ wa pe ki wọn yaa lẹ ẹ nibi ti wọn ti bu u lori ọrọ gbedeke owo tuntun naa.

Wọn tun ni kile-ẹjọ paṣẹ fun banki apapọ, atawọn banki gbogbo, awọn alagbata wọn, awọn ejẹnti atawọn alajọṣe okoowo wọn pe ẹnikan o gbọdọ kọ owo atijọ igba Naira (N200), ẹẹdẹgbẹta Naira (N500) ati ẹgbẹrun kan Naira (N1,000) ṣaaju tabi lẹyin ọjọ kẹwaa, oṣu Keji yii, ti wọn ti n fọnrere ẹ naa.

Ninu iwe ipẹjọ naa, wọn sọ funle-ẹjọ pe: “Ti ilẹ-ẹjọ ọlọla yii o ba da sọrọ yii, ipọnju to lekenka ati inira gidi to n koju ijọba ipinlẹ Kaduna, Kogi ati Zamfara, atawọn olugbe ibẹ ko ni i rọlẹ, latari bi ko ṣe si owo tuntun to pọ to, tijọba o si faaye ọjọ gbọọrọ to to silẹ fawọn eeyan lati fẹsọ paarọ owo naa. Wọn ni lọwọlọwọ, atijẹ atimu ti n di inira fawọn eeyan ipinlẹ awọn, eto atunto owo ti banki apapọ si gun le yii n ṣakoba gidi fun iṣẹ ounjẹ oojọ awọn araalu tawọn n ṣejọba le lori. Wọn lawọn agbegbe kan tiẹ wa nipinlẹ koowa wọn to jẹ pe o fẹrẹ ma ṣee ṣe fawọn eeyan lati ri owo tuntun naa gba, wọn ni titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn kan o ti i mọ ila towo ọhun kọ, boya dudu ni o abi funfun, tori ko si banki lawọn agbegbe ati arọko kan, ibi ti banki tabi awọn oni-POS wa si wọn jinna bii ẹni n lọ idalẹ ni.

Wọn tun ṣalaye pe aibalẹ ọkan, akọlukọgba, ija ati aifararọ ti n ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ to pẹjọ yii, tori bawọn eeyan ṣe n wo gbedeke ọjọ ti owo ọwọ wọn yoo di kọndẹ mọ wọn lọwọ, ti wọn o si rọna ati gba tuntun bọrọ, bẹẹ lara n kan wọn si i.

Wọn tun rọ ile-ẹjọ to ga ju lọ pe ki wọn ba awọn ṣedajọ ọrọ yii ni igbona-igbooru la a jẹ oku ọpọlọ, wọn ni ki wọn ma ṣe jẹ ki ipinnu wọn lori ẹbẹ awọn falẹ, tori aanu awọn araalu n ṣe awọn gidi.

Ṣa, wọn ti gba iwe ipẹjọ awọn gomina yii wọle, wọn si ti ni ki wọn ṣe ẹda rẹ ṣọwọ si Buhari nipasẹ Malami, lẹyin eyi nile-ẹjọ naa yoo pinnu ọjọ ti igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹjọ naa.

Leave a Reply