Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Nnkan o ṣẹnure fawọn arinrin-ajo to fẹẹ gba agbegbe Road-block, eyi to wa laarin gbungbun oju ọna marosẹ Ileṣa-Akure-Ọwọ, niluu Akurẹ, kọja laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pẹlu bi wọn ṣe di opopona ọhun pa patapata lasiko tawọn ọdọ kan n fẹhonu han lori ọrọ ọwọngogo epo bẹntiroolu ati owo Naira to n lọ lọwọ.
Aago meje aarọ ko ti i lu tawọn olufẹhonu ọhun fi de si ikorira naa, ọkọ ajagbe nla meji ni wọn fi di ọna marosẹ to wa lati apa Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, pa bamubamu, ohun kan naa ni wọn tun ṣe si opopona to lọ si Ọwọ, Benin ati agbegbe Oke-Ọya, to si jẹ pe bakan naa lọmọ tun ṣori ni ọna to wọ aarin igboro Akurẹ.
Gbogbo bi ifẹhonu han naa ṣe n lọ lawọn ọlọpaa duro wamu wamu lati ri i daju pe ẹnikẹni ko da omi alaafia ilu ru tabi ki awọn janduku kan ja iwọde ọhun gba mọ wọn lọwọ.
Ariwo ti awọn tinu n bi ọhun fi bọnu lasiko iwọde naa ni pe awọn ko fẹ ọrọ ọwọngogo epo mọ, bẹẹ ni nnkan abuku ni ki eeyan lowo ara rẹ si banki ko tun maa ra owo naa nigba to ba fẹẹ gba a jade lati lo o fun anfaani ara rẹ.
Ọkan ninu awọn olufẹhonu han ọhun, Oluyẹmi Fadipẹ, to ba awọn oniroyin sọrọ ṣalaye pe awọn n gbe igbesẹ naa lati jẹ ko di mimọ fun ijọba pe inu awọn eeyan ko dun rara fun iya ajẹpalori ti wọn n jẹ lori iṣẹlẹ ọwọngogo epo ati owo Naira.
O ni awọn tete n sọrọ soke bayii ki ijọba tete wa nnkan ṣe nipa iya ainidii ti wọn fi n jẹ awọn araalu latari eto buruku ti wọn gbe kalẹ ọhun.
Lori ọrọ epo bẹntiroolu, o ni awọn n fẹ ki ijọba gbe igbimọ to nitumọ kan kalẹ, eyi ti yoo maa bojuto iye ti wọn ba n ta jala epo, nitori eyi nikan lo le fopin si iwa ika ati alailaaanu awọn alagbata epo kan ti wọn n fara ni awọn araalu nipasẹ owo gegere ti wọn n ta epo wọn.
Ni ti owo Naira, Fadipẹ ni awọn mẹkunnu lo n jiya ju lọwọlọwọ lori ọrọ pasipaarọ Naira ti ile-ifowopamọ apapọ kede rẹ, o ni ṣe lo yẹ ki wọn ṣi faaye gba nina owo Naira atijọ ati tuntun titi ti awọn eeyan ko fi ni i ri owo atijọ yii nita mọ.
Ọkan ninu awọn aṣoju ẹgbẹ akẹkọọ lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Babatunde ninu ọrọ tirẹ ni ti ijọba apapọ atawọn oloṣelu ba fẹẹ ba ara wọn ja, o yẹ ki wọn mọ ọna ti wọn yoo gba ṣe e dipo ki wọn maa fiya jẹ gbogbo araalu nitori ara tiwọn.
Ọjọ mẹta lo ni awọn ti pinnu lati fi ṣe iwọde alaafia naa, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee si ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii, o ni awọn ṣetan lati tẹsiwaju lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ, ti ijọba ba fi kọ lati da awọn lohun awọn nnkan ti awọn n beere fun.